Emir Sanusi: Kò dára báwọn gómìnà, mínísítà kò se yọjú sípàdé ìdókòwò

Emir Mohammadu Sanusi kejì Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Emir Sanusi korò ojú sí ìwà àílákàsí àwọn alásẹ tí ọ̀rọ̀ ìdókówò náà kàn ní Nàíjíríà

Emir tìlú Kano, Mohammadu Sanusi kejì, ti bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn gómìnà àtàwọn mínísítà tó yẹ kí wọn sọ̀rọ̀ níbi àkànse ètò kan láti fa ojú àwọn olùdókòwò mọ́ra sí orílẹ̀èdè Nàíjíríà, èyí tò wáyé ní ilé Nàíjíríà, ní ìlú Washinton, lórílẹ̀èdè Améríkà.

Ètò náà, tí wọn pè ní ìpàdé ìdókówò láàrin Amẹ́ríkà àti Nàíjíríà, ni iléesẹ́ asojú Nàíjíríà tó wà ní Amẹ́ríkà sètò pẹ̀lú léesẹ́ aládàání kan.

Àfojúsùn ìpàdé náà ni láti kó àwọn alásẹ ní Nàíjíríà àti ní Amẹ́ríkà sábẹ́ òrùlé kan pẹ̀lú àwọn oníléesẹ́ aládàáni, olùdókòwò, àtàwọn ọ̀gá àgbà iléesẹ́ ńláńlá.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionObinrin Akansẹ: Ẹsẹ kiku bi ojo kọ mi lati di alagbara

Lásìkò tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, Emir Sanusi korò ojú sí ìwà àílákàsí àwọn alásẹ tí ọ̀rọ̀ ìdókówò náà kàn ní Nàíjíríà.

Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wọn tó tíì dé lásìkò tó yẹ kí ìkọ̀ọ̀kan wọn sọ̀rọ̀

Ní ibi ìpàdé náà ni wọ́n ti ń retí igbákejì ààrẹ, Yẹmí Ọsìnbájò, mínísítà fún ètò ẹ̀náwó, àti akẹẹgbẹ́ rẹ̀ ní ẹ̀ka epo rọ̀bì, ètò ọ̀gbìn, ètò ìròyìn, ìmọ̀ sáyẹ́ńsì,ohun àlùmọ́ọ́ní ilẹ̀ àti mínísítà fétò okoòwò, sùgbọ́n kò sí ẹnikẹ́ni nínú wọn tó tíì dé lásìkò tó yẹ kí ìkọ̀ọ̀kan wọn sọ̀rọ̀.