Bùhárí: Fáwẹ̀hìnmi jà fún òsèlú alágbádá pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀

Olóògbé Gani Fáwẹ̀hìnmi Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Olóògbé Gani Fáwẹ̀hìnmi jà fún òsèlú alágbádá, tó sì dúró tìí pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀

Yorùbá ní báa kú làá dère, èèyàn kò sunwọ̀n ní ààyè. Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú ìlúmọ̀ọ́ká ajàfẹ́tọ̀ọ́ ẹni àti agbẹjọ́rò nnì, olóògbé Gani Fáwẹ̀hìnmi, ẹni tó pé ọgọ́rin ọdún lọ́jọ́ àìkú, tí ọ̀pọ̀ ọmọ Nàíjíríà, tó fi mọ́ ààrẹ Muhammadu Bùhárí, sì ń rọ òjò ìkínni sórí rẹ̀ ní sàárè.

Gẹ́gẹ́ ààrẹ Bùhárí ti kọrin re kìí, "Olóògbé Gani Fáwẹ̀hìnmi jà fún òsèlú alágbádá, tó sì dúró tìí pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀"

Àtẹ̀jáde kan tí iléesẹ́ ààrẹ fisíta ní, agbẹjọ́rò náà jẹ́ ẹ̀rí ọkàn orílẹ̀èdè yìí, ìlúmọ̀ọ́ká ajàfẹ́tọ̀ọ́ mẹ̀kúnnù àti aláàbò ètò òsèlú alágbádá.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ààrẹ Bùhárí wá rọ tàgba-tèwe ọmọ Nàíjíríà láti fi akọni òǹkọ̀wé àti ẹlẹ́yinjú àánú náà se àwòkọ́se rere, ẹni tí kìí se ẹlẹ́yàmẹ̀yà, tí kìí se alájẹbánu, tó sì tún nígbàgbọ́ nínú ìrẹ́pọ̀ àti ìlọsíwájú orílẹ̀èdè yìí.

Ìjọ̀ba ìpínlẹ̀ Èkó yóò sí ère Gani Fáwẹ̀hìnmi

Wàyí ò, ìjọ̀ba ìpínlẹ̀ Èkó yóò sí ère Gani Fáwẹ̀hìnmi kan tó gbẹ́ sí ibùdó ìgbafẹ́ kan tó wà ní agbègbè Ọjọ́ta láti sàmì ọgọ́rin ọdún olóògbé náà.

A gbọ́ pé Gómìnà Akinwùnmí Ambọde, àwọn mọ̀lẹ́bí Gani Fáwẹ̀hìnmi, àwọn ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ẹni, àtàwọn èèkàn ìlú míì, ni yóò lọ sí ère ọ̀hún.