NEMA- Àwọn asoàdóikúmọ́ra pa awọn olùjọ́sìn ni Borno

Borno Mosque Image copyright Getty Images

Àárọ̀ ọjọ́ àìkú ni awọn asoàdóikúmọ́ra méjì, to jẹ́ ọkùnrin kan ati obìnrin kan, tí wọ́n fura sí gẹ́gẹ́ bi ọmọ ikọ̀ Boko Haram ya wọ inú Mọ́sálásí kan ni agbègbè Bama Dina ní ìpínlẹ̀ Borno ti wọ́n si gbẹ̀mí àwọn eniyan.

Àjọ toó n rí sí ìsẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì lorilẹede Naijiria NEMA ẹ̀ka ìwọ̀oòrùn àríwá ló fìdí ọ̀rọ̀ naa múlẹ̀.

Oun tó tó èèyàn mẹ́rin ni wọ́n sọ pe o ti pàdánù ẹ̀mí wọn ninu ìsẹ̀lẹ̀ ọun.

Awọn asoàdóikúmọ́ra ọ̀ún ni a gbọ́ pe wọ́n tọ́ déédé ọmọ ọdún mẹ́tàlá sí mẹ́rìnlá.

Awọn agbófinró ni a gbọ́ pe wọ́n ti débi ìsẹ̀lẹ̀ ọ̀ún, ti wọ́n sì ti gbìyànjú lati gbé awọn ti wọ́n farapa lọ sí ilé ìwòsàn.