Ọlọ́pàá: Kò yẹ kí Dino jáde ní Nàíjíríà

Dino Mélayé ń rẹ́rìń Image copyright @dino_melaye
Àkọlé àwòrán Iléesẹ́ ọlọ́pàá ti kéde sáájú pé àwọn ń wa Dino Mélayé

Ìròyìn kan tó ń tẹ̀ wá lọ́wọ́ ní, asòfin àgba kan, Senetor Shehu Sani, àti olórí ilé asojú-sòfin, Yakubu Dogara, ti kọọ́ sójú òpó Twitter wọn pe àwọn ọlọ́pàá ti fi Dino Mélayé sílẹ̀.

Àarọ̀ ọjọ́ ajé ni ìròyìn gbalẹ̀ kan pe àwọn ọlọ́pàá ti mú Dino Melaye.

Wàyí o, iIléesẹ́ ọlọ́pàá ní orílẹ̀èdè Nàíjíríà ti sàlàyé ìdí tí wọn fi mú Sẹ́nẹ́tọ̀ tó ń sojú ẹkùn ìdìbò ìwọ̀ òòrùn Kogí, Dino Mélayé, ní pápákọ̀ òfurufú Nnamdi Azikwe ní ìlú Àbújá ní àárọ̀ ọjọ́ Ajé.

Orí ẹ̀rọ Twitter rẹ̀ ni Mélayé ti kéde pé àwọn ọlọ́pàá ti mú òun lásìkò tí òun ń rin ìrìn àjò kúrò ní orílẹ̀èdè yìí, lọ sí Morocco fún isẹ́ ìlú kan tí ìjọba àpapọ̀ se onígbọ̀wọ́ rẹ̀.

Image copyright @dino_melaye
Àkọlé àwòrán Iléesẹ́ ọlọ́pàá ní, àwọn ti fi orúkọ Mélayé tó iléesẹ́ ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ àgbáyé, Interpol, létí

Iléesẹ́ ọlọ́pàá ní orílẹ̀èdè Nàíjíríà ti sàlàyé ìdí tí wọn fi mú Sẹ́nẹ́tọ̀ tó ń sojú ẹkùn ìdìbò ìwọ̀ òòrùn Kogí, Dino Mélayé, ní pápákọ̀ òfurufú Nnamdi Azikwe ní ìlú Àbújá ní àárọ̀ ọjọ́ Ajé.

Orí ẹ̀rọ Twitter rẹ̀ ni Mélayé ti kéde pé àwọn ọlọ́pàá ti mú òun lásìkò tí òun ń rin ìrìn àjò kúrò ní orílẹ̀èdè yìí, lọ sí Morocco fún isẹ́ ìlú kan tí ìjọba àpapọ̀ se onígbọ̀wọ́ rẹ̀.

Ìkéde àkọ́kọ́ tí Mélayé fi ránsẹ́ sórí Twitter ló wà lókè yì, àmọ́ lẹ́yìn wákàtí kan ló tún fi òmíràn s'óde.

Bẹ́ẹ̀ bá gbàgbé, iléesẹ́ ọlọ́pàá ti kéde sáájú pé àwọn ń wa Dino Mélayé lórí ẹ̀sùn pé àwọn afurasi kan fẹ̀sùn kàn án pé òun ló ń kó ìbọn fún àwọn.

Iléesẹ́ ọlọ́pàá ní, àwọn ti fi orúkọ Mélayé tó iléesẹ́ ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ àgbáyé, Interpol, létí, tí wọn sì ti fi orúkọ rẹ̀ sí ara àwọn afurasí tí wọ́n ń wá.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ ní ẹ̀kúnkúnrẹ́ fún BBC, Ọ́gá àgbà iléesẹ́ ọlọ́pàá fún ẹkùn keje, Ọ̀gbẹ́ni Istifanus Sunday Bako ní, Dino ń yọ́ jáde ní Nàíjíríà lawọn se múu.

"Orúkọ Dino Mélayé wà lára àwọn afurasí tí iléesẹ́ ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ àgbáyé, Interpol, ń wá. A sì ri pé ó ń yọ́ kẹ́lẹ́ jáde kúrò ní Nàíjíríà, èyí tí kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀, la se múu."

Orúkọ Mélayé kò sí lára àwọn afurasi tí wọn ń wá ní Interpol

Èyí ló wá mú kí BBC lọ sorí òpó ìkànsíra ẹni tó jẹ ti iléesẹ́ ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ àgbáyé, Interpol, láti mọ̀ bóyá orúkọ Mélayé wà lára àwọn afurasi tí wọn ń wá, àmọ́ a ríi pé orúkọ mélayé kò sí níbẹ̀.