Ìkọlù Benue: Ọ̀dọ́, PFN, CAN tutọ́ sókè lórí ikú olùjọ́sìn

Àwọn ọ̀dọ́ tó ń fọnmú nítorí ìkọlù darandaran Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti ń késí ìjọba Nàíjíríà láti wá ojútùú sí ìkọlù darandaran

Yorùbá ní ikú tó ń pa ojúgbà ẹni, òwe ńlá ló ń pa fún ni, èyí ló mú káwọn ọ̀dọ́ yíká ìpínlẹ̀ Benue fi fọnmú nítorí ìkọlú àwọn darandaran tó rán àwọn olùjọ́sìn ìjọ àgùdà bíi ogún sí ọ̀run ọ̀sán gangan ní ọjọ́ aje.

Ogúnlọ́gọ̀ àwọn ọ̀dọ́ náà ló yarí kanlẹ̀ sójú pópó, tí wọ́n sì ń sun iná láwọn òpópónà kan ní ìlú Makurdi, tíí se olú ìlú ìpínlẹ̀ náà.

Gbogbo àwọn ọjà , ilé ìfowópamọ́ àti ilé ẹ̀kọ́ ní ìlú ọ́hùn ni wọ́n tì pa, táwọn òbí sì ń sáré lọ mú àwọn ọmọ wọn nílé ẹ̀kọ́ nítorí kí ojú má rí ibi, ẹsẹ̀ ni òògùn rẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAwọn daran daran fi ọbẹ ge baba mi lori - ọmọ ọdun mọkanla

Bí ó tilẹ̀ jẹ́pé àwọn agbófinró gbàródan sáwọn agbègbè kan ní ìlú Makurdi, síbẹ̀, àwọn èèyàn ìlú náà sì ń kó àyà sókè pé eégún àwọn darandaran náà tún leè sẹ́ lẹ́ẹ̀kan síi, tí wọn sì ń késí ìjọba ìpínlẹ́ náà láti dààbò bo àwọn àti dúkìá àwọn lọ́wọ́ ikú àti àdánù.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àìmọye ìgbà ni darandaran ti rán ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn ìpínlẹ̀ Benue sí ọ̀run ọ̀sán gangan

Ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ àpapọ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi CAN àti PFN ní ìpínlẹ̀ Benue ti ń gbarata pé ìgbàwo ni ìkọlù àwọn darandaran yóò d'ohun ìtàn ní ìpínlẹ̀ náà nítori ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàíjíríà yókù ni kò leè fi ẹ̀dọ̀ lórí òróǹro mọ́.

Àwọ́n èèyàn Benue ńbẹ àwùjọ àgbáyé láti gba àwọn

Ààrẹ ẹgbẹ́ PFN ni ìpínlẹ̀ Benue, Àlúfà Felix Omobude àti amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ ààrẹ CAN, Báyọ̀ Ọládèjì ní àwọn iléesẹ́ agbófinró ti já àwọn ọmọ orílẹ̀èdè yìí kulẹ̀.

Wọ́n wá ńbẹ àwùjọ àgbáyé láti gba àwọn nítorí àìlásọ lọ́rùn pààká ni àwọn ìsẹ̀lẹ̀ ìkọlù darandaran yìí jẹ́, ó sì ti di àpérò fún gbogbo àwọn ọmọ̀ eríwo báyìí.