Ọmọ Nàíjíríà: Eré ìtàgé lágbo òsèlú bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn BB Naija

Dino Melaye Image copyright @dino_melaye
Àkọlé àwòrán Ó tó ọ̀sẹ̀ méjì tí ọlọ́pàá ti kéde pé wọn ń wá Mélayé

Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé onírúnirú ọ̀bẹ làá rí lọ́jọ́ ikú erin, èyí ló mú kí èrò àwọn ọmọ Nàíjíríà se ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nípa bí ìjọba àpapọ̀ se mú Sẹ́nẹ́tọ̀ Dino Mélayé àti ọ̀pọ ìsẹ̀lẹ̀ míì tó tẹ̀le, tó fi mọ́ bí wọn se ló jábọ́ lẹ́yìn ọkọ̀.

Ń se ni ojú òpó Twitter kún àkúnfàya nípa ìsẹ̀lẹ̀ yìí. Bí àwọn ọmọ Nàíjíríà kan se ń tàbùkù ìjọba lórí [bó se gbé Dino, ni àwọn mìíràn ń kan sáárá sí ìjọba pé bẹ́ẹ̀ ni ọmọkùnrin ń se.

Ẹ jẹ́ ká wo èrò àwọn ọmọ Nàíjíríà lóríi Twitter ní sísẹ̀ ń tẹ̀lé:

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Dino melaye gba ìdáǹdè lọ́wọ́ ọlọ́pàá

Sé wọ́n lè yọ Sẹ́nátọ̀ nípò?

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAgbẹnusọ Mélayé: Dino ti lọ yọjú sọ́dọ̀ ọlọ́paa SARS

Ọmọọba Adélàjà @AdelajaAdeoye ní, pẹ̀lú bí wọn se gbé Dino yìí, màrìwò la tíì rí, egúngún sì ń bọ̀ nítorí ọ̀pọ̀ àwọn olùdíje fún ipò ààrẹ ni wọn yóò rán lẹ́wọ̀n. Òwe ńlá sì ni bí wọn se lọ yẹ ilé Gómìnà Tambuwal wò, lọ́sẹ̀ díẹ̀ sẹ́yìn, ń pa fún ni.

Ibrahim Ijaọla @ijaola_ibrahim ti wi, ó yẹ kí OBJ, IBB àti GEJ máa gbáradì nítorí ikú tó ń pa ojúgbà ẹni, òwe ńla ló ń pa fún ni.

Gloria Adagbọn @gloria_adagbon ní, pẹ̀lú ìwà Dino táa mọ̀, a jẹ́ pé ká máa retí orin ‘àjekú ìyà’ míì láìpẹ́ ni.

Ojoawo Gbenga @gbengusgbengus ní ọ̀daràn pọ́ńbélé nìkan ni yóò já bọ́ láti inú ọkọ̀ ọlọ́pàá nígbà tí wọn bá múu.

"Èmi kìí se olólùfẹ̀ẹ́ Dino, sùgbọ́n bí wọn se mú Dino dà bíi ìgbà tí wọn mú ìjọba tiwantiwa. Bí ẹ bá pa Dino, ẹ ti pa ìjọba tiwantiwa nìyẹn"@NnadiEdwin25

"Big Brother ti tán, gbogbo nkan ti ń padà bọ̀ sípò, tó fi mọ́ bí wọn se mú Dino Mélayé"@Bolanle_AA.