Ìkọlù darandaran: 700 èèyàn lẹ̀mí wọn bọ́ sínú ìkọlù

Pósí àwọn èèyàn tí darandaran ti pa sẹ́yìn Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àìmọye ìgbà ni darandaran ti rán ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn ìpínlẹ̀ Benue sí ọ̀run ọ̀sán gangan

Awọn ọdọ, Ajọ ọmọ lẹyin Kristi, CAN ati PFN lo ti sọrọ lodi si isekupani awọn Fulani darandaran si Ijọ Aguda nibi ti wọn ti pa Fada meji pẹlu ọmọ ijọ mẹtala.

Laipe yii ni ajọ ajafẹtọ ọmọniyan lagbaye, Amnesty International (AI), sọ wipe ija laarin awọn Fulani darandaran ni ipinlẹ Adamawa, Benue, Taraba, Ondo ati Kaduna ti jasi iku ẹẹdẹgbẹrin eniyan,

Ajọ Amnesty International fi kun wipe eniyan bii ejidinlaadọsan lo si ti papoda ninu ikọlu awọn darandaran ni Osu Kinni, ọdun 2018.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌlọ́fà: A ti ń kọ́lé fún ọlọ́pàá kògbérégbè

Ninu atẹjade awọn ajọ ọmọ lẹyin Kristi lorilẹede Naijiria, CAN, o sakawe iye igba ti awọn Fulani ti se ikọlu si Benue lati ọ̀dun 2013, tawọn darandaran naa ti bẹrẹ ikọlu.

Iye igba ti awọn darandaran ti se ikọlu si Adamawa, Benue, Taraba, Ondo ati Kaduna

 • February 2013; Awọn Fulani pa ọgọọrọ eniyan ni Benue
 • May 7, 2013: Awọn 47 ni wọn yinbọn pa nigbati wọn n sinku awọn ọlọpaa meji ti awọn Fulani darandaran sekupa
 • Feb 20-21, 2014: Awọn Fulani darandaran pa eniyan 35, ọgọọrọ si di alainile gbe
 • March 6, 2014: Awọn Fulani darandaran pa eniyan 30 ni agbeegbe Kwande, Katsina
 • March 23, 2014: Eniyan 25 padanu ẹmi wọn nigba ti 50 si farapa nibi ikọlu awọn darandaran si agbeegbe Gbajimba,ni Benue
 • March 15, 2015: Wọn se ikọlu si agbeegbe Egba ni Agatu LGA to si le ni eniyan 90 pẹlu obinrin ati ọmọde ti ẹmi wọn lọ si.
 • April 27, 2015: Awọn eniyan 28 ku ni ikọlu si ijọba ibilẹ Guma ni Benue
 • Feb 21-24, 2016: O le ni eniyan 500 to ku, ti ọgọọrọ si di alainile gbe nibi ikọlu si agbeegbe ijọba ibilẹ Agatu ni Benue
 • January 24, 2017: Ko din ni eniyan 15 ti awọn Fulani darandaran ti gba ẹmi wọn ni ibi ikọlu awọn Fulani si agbeegbe naa.
 • December 31, 2017 si January 2, 2018: Awọn Fulani darandaran pa eniyan mẹtalelaadọrin ni Benue
 • January 10, 2018; Eniyan 55 lo padanu ẹmi wọn ni Taraba
 • Jan 14 2018; Eniyan 10 ni awọn Fulani darandaran pa ni ipinlẹ Kaduna
 • February 12, 2018; Afunrasi Fulani darandaran pa agbẹ kan nilu Ipao Ekiti
 • February 13, 2018; Awọn darandaran le awọn osisẹ ijọba kuro ni ile isẹ wọn ni Akure
 • March 6, 2018; Fulani darandaran pa eniyan 24 ni Benue
 • April 5, 2018; Awọn darandaran pa eniyan mẹrin ni Taraba
 • April 12, 2018; Eniyan marun gbẹ ẹmi mi ninu ikọlu awọn darandaran si Nasarawa
 • April 13, 2018; Oku mẹẹdọgbọn tun sun nibi isinku apapọ ni Ikọlu Plateau
 • April 15, 2018; Darandaran tun gbẹmi mẹẹdọgbọn ni Kogi
 • Èèyàn mẹ́wàá kú nínú ìkọ̀lù tuntun ni Benue 21 04 2018