Wọ́n ké sí ààrẹ láti wá dáhùn ìbéèrè lórí àwọn ẹ̀mí tó nù

Ààrẹ Mohammadu Buhari Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ilé asòfin ní kí Buhari wá sọ tẹnu ẹ

Wọ́n ti ké sí ààrẹ orílẹ̀èdè Nàìjíríà, Mohammadu Buhari kó wá farahàn níwájú ilé ìgbìmọ̀ asojú-sòfin láti dáhùn àwọn ìbéèrè nípa ìsẹ̀lẹ̀ ibi tó wáyé ní ààrin gbùngbùn Nàìjíríà èyí tó ti fa ikú ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́dún yìí.

Ìgbésẹ̀ àìwọ́pọ̀ yìí wáyé ní kété tí ìròyìn ìkọ̀lù òjijì sẹlẹ̀ sí ìjọ Kátólíkì ní ìpínlẹ̀ Benue èyí tó mú ẹ̀mí ènìyàn mẹ́rìndínlógún lọ tó fi mọ́ fadá méjì.

Àwọn òsìsẹ́ aláàbò tí se se se lórí kíkojú ìkọlù gbogbo ìgbà láàrin àwọn àgbẹ̀ àti fúlání darandaran.

Ìsẹ̀lẹ̀ àìbalẹ̀ ọkán yìí wá sé gẹ́gẹ́ pẹ̀lú sùnmọ̀mí tó ńwáyé ní ìhà àríwá orílẹ̀èdè Nàìjíríà látọwọ́ ẹgbẹ́ Boko Haram.

Sùgbọ́n kò tíì yé bóyá ààrẹ Buhari yóò gbà láti fara hàn níwájú ilé ìgbìmọ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: