NUC: Ayédèrú ìwe ẹ̀rí ni sẹ́nétọ̀ Foster Ogola ń lo

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNUC: 'Ayédèrú n'ìwé ẹ̀rí sẹ́nétọ̀ Foster'

Sẹ́nétọ̀ tó ń sojú ẹkùn ìdìbò ìwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ Bayelsa, Foster Ogola, ni wọ́n ti se ọ̀fintótó ẹ̀sùn pé o ń lo ayédèrú ìwé ẹ̀rí.

Àjọ tó n mojútó àwọn ilé ìwé gíga fásitì lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, NUC sọ wí pé oyè PhD tí sẹ́nétọ̀ Ogola ní jẹ́ ayédèrú nítorí pé ilé ìwé tí ọ̀gbẹ́ni Ogola ní òun ti gbá ìwé ẹ̀rí náà wà lára àwọn ilé ìwé gíga fásitì tí wọn kò fọwọ́sí tí àjọ náà sì fẹ́ tì pa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sẹ́nétọ̀ Ogola tó ń sàfihàn àseyọrí ìwé ẹ̀rí tó ti ń lò ó fún iṣẹ́ òsèlú rẹ̀ látẹ́yìn wá ni iṣẹ ọwọ awọn to n lepa aṣeyọri oun lẹnu oṣlu lo wa nidi rẹ.

Ní báyìí, ìwádìí fi hàn pé àwọn ìwé ẹ̀rí oyè PhD tó gbà nínú ìmọ̀ adarí krìstẹ́nì láti fásitì tí àjọ NUC kò fọwọ́ sí jẹ́ ayédèrú.

Àtẹ̀jáde kan tó wá láti ọ́fììsì akọ̀wé àjọ NUC, fihàn wí pé fásitì, Gospel Missionary Foundation (GMF), tíí se ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì onímọ̀ nípa ẹ̀sìn krìstẹ́nì níbi tí sẹ́nétọ̀ Foster ti gba ìwé ẹ̀rí PhD rẹ̀ hàn nínú ìwé àwọn ilé ìwé gíga fásitì àìtọ́ tí àjọ náà fẹ́ tì pa.