UN: Ìkọlù Boko Haram, darandaran pẹ̀lu ááwọ̀ ósèlú ń dẹ́rù bà wá

Awọn asia orilẹ-ede to wa ninu ajọ isọkan agbaye Image copyright Getty Images

Igbimọ eleto aabo labẹ ajọ isọkan orilẹ́-ede agbaye (United Nations), UN, ti figbe bọnu pe laasigbo to n waye lẹka eto oselu, ikọlu Boko Haram, iya to n jẹ awọn eeyan ti ko nile lori ati aawọ ojoojumọ laarin awọn agbẹ ati darandaran ni orilẹ-ede Naijiria to n peleke sii, n kọ oun lominu.

Ajọ UN ni ọ̀pọ̀ ikọlu naa, ti wa di ailasọ lọrun paaka, o si ti di apero fun awọn ọ̀mọ eriwo bayii nitori obiti-biti ofo ati adanu ojojumọ, ni ilẹ Naijiria n ri lawọn agbọn ti ajalu ọhun ti n waye.

Image copyright Getty Images

Atẹjade kan ti ajọ United Nations fi sita lọjọ Aiku, wa bu ẹnu atẹ lu iwa ipa, rogbodiyan ati pakaleke to gba ilẹ kan ni tibu-tooro orilẹ-ede Naijiria ati awọn orilẹ-ede to yii ka.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌyá Darasimi: Ọlọ́run fi ìbejì rẹ̀ mí lẹ́kún, lẹ́yìn ikú Darasimi tó mu sódà

Ajọ UN ni, ominu n kọ oun, ti aya oun ko si lelẹ mọ nitori awọn laasigbo yii ati awọn ohun miran to nii se pẹlu eto idibo gbogbo-gboo to n bọ, to fi mọ ọrọ aje ati igbaye-gbadun awọn araalu, ka ma sẹsẹ sọ boo ba o pa, boo ba, ko bu lẹsẹ, ti awọn agbẹ ati daran-daran n se.

Ajọ isọkan orilẹ-ede agbaye naa, to ni bi ara ile ẹni ba n jẹ kokoro buruku, ti a ko ba tete wi fun-un, hẹrẹ-huru rẹ ko ni jẹ ka sun loru, lo mu ki oun tete maa kigbe sita bayii pe, ẹni to ba ni eti ko gbọ, ohun ti ẹmi n sọ fun awọn ijọ.

Image copyright Getty Images

Bakan naa ni ajọ Un tun fi ipaya rẹ han, lori eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria ati iya to n jẹ awọn eeyan, paapa awọn ti ko nile lori lati-pasẹ ikọlu ikọ Boko Haram.

Ajọ naa wa n rọ awọn eeyan ati ajọ ti ipese eto aabo to peye kan ni Naijiria, lati tete pakiti mọlẹ wa wọrọkọ fi sada, lori awọn isẹlẹ naa, ko to bọwọ sori

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn òṣìṣẹ́ iranwo fun àjò United Nation lorile-ede South Sudan ni wọn ti sọnù

Àwọn òṣìṣẹ́ iranwo fun àjò United Nation lorile-ede South Sudan ni wọn ti sọnù

Èka UN tó ń mójú tó àlàáfíà Ọmọniyan sọ pé àwọn ikọ náà jé onírúurú àwọn ènìyàn yọ wá láti oríṣiríṣi àjọ mìíràn, tí wọn sì ń lọ fún àmójútó ohun tí àwọn èèyàn kan nílò.

Oga àgbà kan láti àjọ UN ní orílẹ̀ èdè South Sudan, Alain Noudehou sọ pé ibi tí àwọn ènìyàn Òun wọlé sí ní àwọn kò mọ

O ni botilejepe pé ilahilo wá láàárín ìjọba àti àwọn abajoba sọtẹ̀ lágbègbè tí wọn ti lọ ṣíṣe, ó rọ wọn láti jọ̀wọ́ wọn lálàafia.

Èkejì rèé losu kan tí nkan ń ṣẹlẹ̀ sàwọn òṣìṣẹ́ UN.