Olórí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Michael Adeyemo jáde láyé

Michael Adeyemo Image copyright facebook/Michael Adeyemo
Àkọlé àwòrán LoOlori ile aṣofin ipinlẹ Ọyọ, Michael Adeyemo jade laye

Iroyin ti sọ wi pe, aisan ọkan lo pa Olori ile aṣofin ipinlẹ Ọyọ, Aṣofin Michael Adeyemo.

Olori ile aṣofin ipinlẹ Ọyọ, Aṣofin Michael Adeyemo jade laye lowurọ ọjọ ẹti ni ileewosan Jericho nilu Ibadan.

Ninu ọrọ to ba BBC yoruba sọ, akọwe ipolongo fun ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Ọyọ, ọgbẹni Mojeed Olaoya fidi iṣẹlẹ yii mulẹ

Lasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, wọn ti gbe oku aṣofin Michael Adeyemo si ile igbokusi.

Ile aṣofin ipinlẹ Ọyọ ko tii fi iroyin sita lori iku rẹ.