Ohun ìjà Nuclear: Orílẹ̀èdè Korea méjèèjì ṣ’àdéhùn lẹ́yìn ìjíròrò

Kim Jong-un ati Moon Jea-in Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Orilẹede mejeeji ti pinu lati seto alaafia laarin orilẹede mejeeji lẹhin ogun Korea to waye lọdun 1953

Awọn adari orilẹede North Korea ati South Korea ti gba lati sisẹ pọ lati fopin si awọn ohun ija oloro asekupani nuclear to wa ni erekuṣu, lẹyin ti wọn sepade fun igba akọkọ.

Ikede naa waye lẹyin ti Kim Jong-un ti orilẹede North Korea ati Moon Jae-in ti South Korea fọrọ jomitoro ọrọ lẹnu ibode orilẹede mejeeji.

Orilẹede mejeeji si ti pinu lati seto alaafia laarin orilẹede mejeeji lẹhin ogun Korea to waye lọdun 1953.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ, orilẹede mejeeji ko fi lede bi wọn yoo se dawọ ohun ija oloro asekupani nuclear duro lẹkun erekusu wọn, eyi to mu ki awọn eniyan o maa se iyemeji lori ipade awọn adari mejeeji.