Britain: Àbẹ̀wò Ọmọọba Charles yóò mú kí àjọsejọ̀ túbọ̀ dán mọ́rán

Ọmọ ọba Charles

Oríṣun àwòrán, UK IN NIGERIA

Àkọlé àwòrán,

Ọmọ ọba Charles sàbẹ̀wò sí Nàìjírìa

Ọmọọba ilẹ Gẹẹsi, Àrẹ̀mọ ilẹ̀ Wales, Charles ati iyawo rẹ, ọmọọbabinrin Camilla ti gunlẹ si orilẹede Naijiria lọjọ Iṣẹgun.

Papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe nilu Abuja ni wọn balẹ̀ sí lọsan ọjọ iṣẹgun.

Lara awọn to gba wọn lalejo ni Minisita fun ilu Abuja, Muhammad Musa Bello ati awọn eekan miran ninu ijọba.

Oríṣun àwòrán, @UKinNigeria

Ọmọọba Charles se ayẹwo awọn ọmọogun Naijiria ti wọn wa yẹsi, ki o to lọ si ile ijọba lọ pade Aarẹ Buhari.

Oríṣun àwòrán, @UKinNigeria

Oríṣun àwòrán, @UKinNigeria

Aarẹ Buhari ki Ọmọọba Charles àti ìyàwó rẹ̀, Camilla kaabọ si orileede Naijiria, ti ireti ṣi wa wi pe wọn yoo jiroro lori awọn ọrọ to jọ mọ mimu idagbasoke ba ibasepo laarin Naijiria ati ilẹ Gẹẹsi.

Saaju ni aṣoju ilẹ Gẹeṣi ni Naijiria, Paul Arkwright sọ pe, ọmọọba Charles yoo gbiyanju lati pẹtu si aawọ to n waye laarin awọn agbẹ ati darandaran.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Lekan Kingkong: Níbikíbi tí mo bá wà, màá gbé àṣà Yorùbá ga

Arkwright fi kun ọrọ rẹ pe, abẹwo ọmọọba Charles jẹ ọna kan lati jẹ ki ibaṣepọ to wa laarin orilẹede Naijiria ati Ilẹ Gẹeṣi dan mọran sii.

Bakan naa, ile isẹ ijọba to n ri si ọrọ abẹle sọ pe, Charles atiyawo rẹ yoo ṣepade pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari ati ẹgbẹ oṣelu alatako ni Naijiria, PDP.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọmọ ọba Charles sàbẹ̀wò sí orílẹ́èdè Ghana

Bẹẹni wọn yoo tun kopa ninu igi gbingbin lolu ile isẹ ijọba ilẹ Gẹeṣi nilu Abuja.

Ọjọ mẹta ni ọmọ ọba Charles yoo fi ṣabẹwo si Naijiria, bẹẹ ni o ti ṣabẹwo si orilẹede Afirika mẹrinlelogoji bayii.

Ẹ ku ewu ọmọ tuntun

Oriade ti Cambridge to jẹ ọmọọba Ilẹ Gẹẹsi, Williams ati iyawo rẹ Catherine ti sọ orukọ ọmọ wọn kẹta ni Louis Arthur Charles.

Arthur jẹ ọkan lara orukọ baba ọmọọba naa, Baba Ọbabinrin Ilẹ Gẹẹsi, George Vl ati Baba nla rẹ, Oriade Mountbatten.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Wọn bi Ọmọọbakunrin tuntun naa ni Ọjọ Aje ni ile iwosan ti Saint Mary ni ilu London

Ọmọọbakunrin tuntun naa ni wọn bi laago mọkanla kọja isẹju kan (BST) ni Ọjọ Aje ni ile iwosan ti Saint Mary ni ilu London.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Wọn bi Ọmọọbakunrin tuntun naa ni Ọjọ Aje ni ile iwosan ti Saint Mary ni ilu London

Atẹjade kan lori ẹrọ ikansiraẹni Twitter ti Kensington Palace fidi rẹ mulẹ pe awọn eniyan yoo ma a pe ọmọ tuntun jojolo naa ni ọmọọbakunrin ti ilu Cambridge, ni Ilẹ Gẹẹsi.

Ọmọọba tuntun naa lo se ikarun si ori itẹ Ilẹ Gẹẹsi.