China: Arákùnrin kan gùn akẹẹ́kọ̀ọ́ méje lọ́bẹ pa

Aworan ọlọpaa Image copyright STR/AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán A gbó wí pé akẹ́ kọ̀ọ́ tẹ́lẹ̀ ni ile ẹkọ náà l'arakunrìn ọ̀hún jẹ́

Àwọn aláṣẹ lórílẹ̀-èdè China tí kéde pé okùnrin kan ti gùn akẹ̀kọ̀ọ́ méje lọ́bẹ pá ti o sí da ọgbẹ́ sí àwọn mokandinlogun míràn lára.

Wọn ni ìṣẹlẹ náà wáyé nígbà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà n darí láti ilé ẹkọ wọn.

L'agbegbe Shaanxi to wa ní àríwá lórílẹ̀-èdè náà ni ìṣẹlẹ ọ̀hún tí wọn ni oun lo burú julọ ti waye.

Wọ̀n kò sọ pàtó ìyè ọjọ orí àwọn akẹ̀kọ̀ọ́ tọ́rọ̀ kàn, sugbọn, ìwádìí fí hàn pé ọjọ orí àwọn akẹ̀kọ̀ọ́ ile ìwé gírámà l'agbegbe náà kò jù ọdún méjìlá sí mẹẹdogun lọ.

Ile iṣẹ ọlọ́pàá ní kò tíì sí àlàyé kánkan lórí ohun tó mú kí arakunrin náà hu irú ìwà bẹẹ.

Àwọn tó f'arapa n gbà ìtọjú lọwọ ní ilé ìwòsan

A gbó pé awon ọlọ́pàá sí tí mú arakunrin tó hù ìwà aburú yìí.