2019 Elections: Gómìnà Ọyọ ni yóò díje láti ṣojú gúúsù Ọyọ nilé aṣòfin àgbà

Gomina Abiọla Ajimọbi

Oríṣun àwòrán, @oyostategovt

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Abiọla Ajimọbi ti jáwé olu bori ní idibo abẹ́le APC ni Ipinlẹ Oyo, eyi to sọọ di oludije ẹgbẹ naa fun ipo sẹnetọ fun Guusu Oyo ni idibo 2019.

Gómìnà Ajimọbi tó kọ́kọ́ lo sáà méjì gẹ́gẹ́ bíi gómìnà ni yóò díje láti ṣojú ìhà gúúsù ìpínlẹ̀ Ọyọ nilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà báyìí.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọjọ Iṣẹgun ni awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa yan ni idibo ti wọn ṣe ni awọn ijọba ibilẹ mẹsan to wan ni guusu Oyo.

Ajimobi gbaìbò 2,659 tí alátakò rẹ̀ Fola Akinosun ni ibo 168. O ti kọkọ ṣe aṣofin fun ẹkun naa ni aarin ọdun 2003 ati 2007 labẹ asia ẹgbẹ AD.

Aarọ kutu Ọjọru ni olori igbimọ to ṣe akoso idibo abẹle naa, Oloye Ademola Seriki kede esi ibo naa, eyi to sọ wipe o lọ ni irọwọrọsẹ.

Ko tii pe ọsẹ meji ti Ajimọbi kede erongba rẹ lati dije dupo naa ti idibo naa fi waye.

Àkọlé fídíò,

Osun Election 2018: Aráàlú ní àwọn kò fẹ́ ìjọba elébi mọ́

O sọ nigba naa pe, "Sẹ mọ pe mo fẹ dije si ile asofin agba ilẹ wa, nitori naa ni mo se lọ feto ayẹwo ẹgbẹ wa nilu Abuja, mo si sẹsẹ de pada ni."

Nigba to n mẹnuba ọpọ aseyọri ti ijọba rẹ ti se ni ipinlẹ Ọyọ lati ọdun mẹjọ sẹyin, Gomina Ajimọbi sọ pe, ipinlẹ toun lo tii ni alaafia julọ yika orilẹ-ede yii.

Bakan naa lo kọrin rere ki Abdulsalam Abubakar, to si se apejuwe rẹ bii ololufẹ alaafia, bẹẹ lo tun yonbo ọpọ aseyọri ilẹ ẹkọ giga fasiti Ibadan.

Oríṣun àwòrán, @oyostategovt

BBC Yoruba gbọ pe sẹnetọ to n soju ẹkun idibo guusu Ọyọ, Adesọji Akanbi ti kuro lẹgbẹ APC lọ si ADC, nitori erongba gomina Ajimọbi lati dije fun ipo naa labẹ ẹgbẹ oselu APC.

Ajimọbi daro olori ile asofin Ọyọ to papo da

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Abiola Ajimobi, tí kéde ìdàrò ọlọjọ mẹta fún Olori ile aṣòfin Michael Adeyemọ tó papoda lójó Ẹtí.

Ìkéde náà wáyé nígbà tó ṣe àbẹwò sí ààyé ibi ìgbokuúsí ni ilé ẹkọ fasiti Ibadan ti wọn gbé oku olóògbé sí.

Ìdàrò náà yóò bẹrẹ lójó Ajé tí ṣe ọgbọn ọjọ oṣù yí titi di ọjọ kejì oṣù kàrún.

Bákan náà lo pàṣẹ siso aṣia kalẹ ni ìrántí olóògbé náà.

Ẹni ire lọ

Oríṣun àwòrán, TWITTER/AHMAD ALI

Àkọlé àwòrán,

Akẹgbẹ́ ní Ahmad àti Adeyemo jẹ gẹgẹ bí olórí ilé n'ipinle wọn.

Olori ile aṣòfin ìpínlẹ̀ Kwara, Ahmad Ali ti ṣe àpèjúwe iku olori ile aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọyọ to ṣalaisi, Michael Adeyemo gẹgẹ bí ohun tó dun ni púpọ̀.

Ninu atẹjade kàn láti ọwọ oluranlowo rẹ̀ lórí ètò ìròyìn, Shuaib Abdulkadri, Ahmad ni ògúnná gbòǹgbò nínú àjọ àwọn olórí ile aṣòfin ni Adeyemo.

O kẹ́du[ùn pẹlu awọn ọmọ ipinle Ọyọ àti ìjọba ìpínlè náà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: