Inec: Èsì ìbò ko tó làti yọ Dino Mélayé

Awon osise INEC nibi ti wọn ti n se ayewo oruko awon ti won fe yo Dino Melaye Image copyright @inecnigeria
Àkọlé àwòrán Kò sí ọ̀nà míràn lábẹ́ òfin fún àwọn ará ìlú látí ṣe ìpàdé ìta gbangba láti dìbò yọ Dino Melaye.

Àjọ elétò ìdìbò lórílẹ̀èdè Nàíjíríà, INEC, ní igbésẹ̀ àti yọ Sẹ́nétọ̀ Dino Melaye ni ilé ìgbìmọ aṣòfin àgbà ti fìdí rẹmi nítorí pe idá márùń nínú ọgọ́rùń àwọn ìdìbò tó f'orúkọ sílẹ̀ ní agbègbè ìwọ̀ oòrùn Kogi nikan ló jáde láti wá ṣe àyẹwò orúkọ wọn ní ọjọ́ Àbámẹ́ta.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Ukertor Moti, tó ka èsì náà, sọ nínú fídíò tí àjọ náà gbé jáde lórí Twitter wípé, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé àwọn olùdìbò agbègbè náà ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀tàlélọ́ọ̀dúnrún ó dín mẹ́sàn án lọ (351,146), àwọn tó jáde láti wá ṣe àyẹwò orúkọ náà, kò ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún lọ (20,868).

Image copyright @inecnigeria
Àkọlé àwòrán INEC ni ètò náà lọ ní irọwọrọse.

Ọ̀gá INEC náà sọ pe, àwọn tó fọwọ́ sí ìwé láti yọ Dino Melaye dín diẹ̀ ní ẹgbẹ̀rú lọ́na igba (189,870), ṣùgbọ́n ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, àwọn tí wọ́n yẹ orúkọ wọn wò dín diẹ̀ ní ẹgbẹ̀rú mọ́kàndínlógún (18,742).

•Iye àwọn olùdìbò agbègbè náà - 351,146

•Àwọn tí ó fọwọ́ sí ìwé láti yọ Melaye - 189,870

•Àwọn tí ó jáde láti wá ṣe àyẹwò orúkọ - 20,868

•Àwọn tí wọ́n ṣe àyẹ̀wò orúkọ - 18,742

Ọ̀jọ̀gbọ́n Moti ní pẹlú èsì yí, kò sí ọ̀nà míràn lábẹ́ òfin fún àwọn ará ìlú látí ṣe ìpàdé ìta gbangba tí wọ́n fi lè dìbò yọ Dino Melaye.

Image copyright Dino Melaye/Facebook
Àkọlé àwòrán Kò sí ọ̀nà lábẹ́ òfin fún àwọn ará ìlú látí ṣe ìpàdé ìta gbangba tí wọ́n fi lè dìbò yọ Dino Melaye

E ó rántí wípe iroyin ti kọ́kọ́ tè wá lọ́wọ́ p, iriri oríṣiríṣi lo wáyé ní awon ẹkùn ìdìbò ti àyẹwò orúkọ tí wáyé.

Nínú fọ́nran fidio kan ti o fi ṣọwọ́ sí oju opo Facebook, a rí i ti awọn kàn n yẹ orúkọ tó wà lórí àkọsílẹ wò ti wọn sì ni eniyan kan lo bọwọ luwe ọ̀pọ̀ orúkọ.