Ìjàǹbá márosẹ̀ Ìbàdàn: Ọkùnrín mẹ́fà àti obìnrin mẹ́fa kú

Ero duro si ibi ti ijamba oko ti sele ni oju ona marose Ibadan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìjàǹbá tó ti wáyé lọjú ọ̀nà márosẹ̀ Èkó sí Ìbàdàn ní ọdún2018 kò lóǹkà

Ọkùnrín mẹ́fà àti obìnrin mẹ́fa ni a gbọ pé o gbẹ́mìí mì ni ojú ọnà márosẹ̀ Èkó sí Ìbàdan lọ́jọ́ àbámẹ́ta nígba tí ọkọ̀ akérò kan la orí mọ́ tírélà kan.

A gbọ́ pé ènìyàn márùń ló farapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó wáyé ní agbàgbà Ogunmakin ní ẹ̀gbẹ́ ilé ìjọsìn Foursquare.

Agbẹnusọ fún àjọ ẹ̀ṣọ́ ojú pópó ní Ìpínlẹ̀ Ògún, Babatunde Akinbiyi sọ pé, ọkọ̀ akérò náà yà níbi tí kò ti yẹ kó yà, ló bá la orí mọ́ tírélà tó ń bọ̀ ní iwájú rẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Fún wákàtí mélòó kan, lójú ọnà márosẹ̀ náà ni ọkọ̀ kankan kò le kọjá.

A gbọ́ pé wọ́n gbé àwọn tí ó kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ sí ilé ìgbókùú sí kan ní Ipara, ní Ìpínlẹ̀ Ògún. Àwọn tí ó fara pa ni wọ́n sì gbé lọ sí ilé iwòsàn kan tí ò wa ní ìtòsí ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹlẹ̀.