Joyce Banda: ẹ̀rù agbófinró kò ba mi

Àwòrán Joyce Banda Image copyright AMOS GUMULIRA/AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán Banda ni Ààrẹ àkọ́kọ́ tó pàdánù ibo lórí òye lórílẹ̀-èdè Malawi

Ààrẹ àná lórílẹ̀-èdè Malawi Joyce Banda tó ti kúrò n'ilu láti bí ọdún mẹ́rin sẹ́yìn sọ pé ẹrú kò bá òun bíi ọwọ òfin yóò tẹ òun.

Banda sọ̀rọ̀ òhún lásìkò to ń bá àwọn alátilẹ́yìn rẹ sọ̀rọ ni ilu rẹ ni Domasi.

O ní botile je pé Ìjọba ti ń wá òun fún ẹ̀sùn ikowojẹ òun kò fòyà torí òun kò ṣẹ̀ sófin

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Banda ni Ààrẹ àkọ́kọ́ tó pàdánù ibo lórí òye lórílẹ̀-èdè Malawi nítorí onírúurú ẹ̀sùn pípa owó ìlú ni pónpó tí wọn fi kàn án.

Nínú ìjọba rẹ̀ ẹgbélẹgbẹ mílíọ̀nù dọ́là owó ìlú ni àwọn àmúgbalẹgbẹ rẹ kò jẹ.

Awuyewuye wá pé Ààrẹ obìnrin kejì lafirika yóò díje dupò Ààrẹ nínú ìdìbò ọdún to ń bọ̀.