Àwọn ọmọ Nàíjíríà: Bùhárí gbọdọ̀ sọ́ ẹnu rẹ̀ l‘Ámẹ́ríkà

Aworan aarẹ Buhari ati Trump Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aarẹ mejeeji yoo sọrọ nipa eto aabo, ọrọ ajẹ ati idokowo laarin orilẹede mejeeji

Awọn ọmọ Naijiria ti kan si Aarẹ Buhari lati sọ ọrọ ẹnu rẹ lasiko ipade pẹlu Aarẹ orilẹede Amerika, Donald Trump nibi ipade awọn adari mejeeji ti yoo waye nile ijọ̀ba Amẹrika, White House.

Awọn ọmọ Naijiria naa fi ero wọn han loju opo ikansiraẹni Facebook ti BBC News Yoruba, nibi ti ati bere lọwọ awọn eniyan wipe kini imọran wọn fun Aarẹ Buhari gẹgẹbi o ti gunlẹ si Washington, lati se ipade pẹlu Aarẹ Trump.

Arakunrin Abayomi Adebiyi gba Aarẹ Buhari ni imọran ‘lati ko ara wọn ni ijanu’, ki wọn si ma se sọ ohun to le da orilẹede Naijria ru.

Bẹẹ si ni, Tọba Joseph sọ wipe ki ‘Aarẹ Buhari o ranti wipe awọn ọdọ kii se ọlẹ’, lẹyin ti Aarẹ Buhari sọ laipe yii wipe, ọgọọrọ awọn ọdọ lorilẹede Naijiria ni ko fẹ isẹ se, ti wọn si n gbẹkẹle owo rọọbi.

Aarẹ Buhari to n dije dupo aarẹ fun igba keji lọdun 2019, yoo gbiyanju lati jẹ ki awọn eniyan mọ wipe eto oselu tiwantiwa jẹ oun logun lọpọlọpọ, ati wipe, oun yoo teramọ gbigbogun ti iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria.

Aarẹ mejeeji yoo sọrọ nipa eto aabo, gbigbogun ti awọn agbesunmomi, Ọrọ ajẹ ati idokowo laarin orilẹede mejeeji.

Ifarapẹra laarin aarẹ Naijiria ati aarẹ ilẹ Amerika

  • Awọn mejeeji de ipo aarẹ nigba ogbo wọn
  • Awọn mejeeji o ki n se oloselu tiwantiwa ki wọn to di aarẹ
  • Igboya lai wo oju ẹnikẹni
  • Ẹnu o ki n si lara awọn mejeeji nitori ọrọ enu wọn
  • Buhari ti jagun ri, Trump o ki n se ologun
  • Aarẹ Trump jẹ gbajugbaja onisowo, bẹẹkọ ni ti ti aarẹ Buhari ri.