Gómìnà Àyọ̀délé Fáyóse f'ohùn 'lẹ̀ f'awọ́n alátakò rẹ̀

Gómìnà Àyọ̀délé FáyóseGómìnà Àyọ̀délé Fáyóse Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Gómìnà Àyọ̀délé Fáyóse f'ohùn 'lẹ̀ f'awọ́n alátakò rẹ̀

Gómìnà Àyọ̀délé Fáyóse ti ìpínlẹ̀ Èkìtì ti ta ohùn padà sí àwọn tó pè ní ọlọ̀tẹ̀ tó ní wọ́n ńdúró de ìgbà tí sáà ìsejọba rẹ̀ yóò parí láti dá sẹ̀ríà fún un.

Fáyóse ní "àwọn tó ńdúró de mí lẹ́yìn tí mo bá f'ipò sílẹ̀ yóò se lásán ni".

Ó ní "Pétérù àpáta ni mí. Mo tún ńsọfún yín, àwọn tó bá ńdúró dè mí yóò dúró lásán ni".

Sáà kejì Fáyóse gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì yóò parí ní ọdún yìí. Ó wá fìdíi rẹ̀ múlẹ̀ wípé òun kò bẹ̀rù ẹnikẹ́ni bẹ́ẹ̀ si ni kò ní ẹnikẹ́nií túbá fún pé òun ńjà f'ẹ́tọ̀ọ́ àwọn ènìyàn lọ́nà òtítọ́.

Ó fi kún un wípé, "mo ti se ohun gbogbo, mo ti gbèjà àwọn ọmọ Nàìjíríà pẹ̀lú ọkan ire bẹ́ẹ̀ sì ni mi ò ní ẹnikẹ́nií túbá fún mí ò sì lè ní rárá. Bí ó bá wù wọ́n, kí wọ́n tì mí mọ́lé látòní di ọdún tó mbọ̀... a ti rí àwọn ààrẹ, a ó sì tún rí síi".

Lórí ọ̀rọ̀ bílíọ̀nù kan dollar owó tó sẹ́kù nínú àpò owó epo rọ̀bì, gómìnà dáa lé ìjọba àpapọ̀ lórí àsìlò owónàá tó wà lápò ìjọba léyìí tó rò pé ó yẹ kó wà fún ẹ̀ka ìjọba mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.

Ó ní "gbogbo owó tó bá wọle fún ìjọba ló yẹ kó máa lọ sínú àpò kan tó yẹ kí ẹ̀ka ìjọba mẹ́tẹ̀ẹ̀ta pín. Lónìí, ìjọba ńńá owó tó yẹ fún ẹ̀ka ìjọba mẹ́tẹ̀ẹ̀ta".

Fáyóse tún sàtúnse ìfarajìn rẹ̀ láti dara pọ̀ mọ́ eré ìje gbígbé àpótí ìdìbò ààrẹ ó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ láti má rẹ̀hìn lórí ọ̀rọ̀ náà kódà lójú inúnibíni tí wọ́n bá se síi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: