Ìdí tí ìgbésẹ̀ àtiyọ Dino fi foríṣánpọ́n

Àwòrán Sẹ́nétọ̀ Dino Melaye Image copyright @dino_melaye
Àkọlé àwòrán Sẹ́nétọ̀ Dino Melaye móríbọ́ nínú ìpè fún ìyọkúrònípò rẹ̀ lópin ọ̀sẹ̀ tó kọjá.

Sẹ́nétọ̀ Dino Melaye móríbọ́ nínú ìpè fún ìyọkúrònípò rẹ̀ lópin ọ̀sẹ̀ tó kọjá.

Àkókò nìyí tí irúfẹ́ ìgbésẹ̀ báyìí yóò wáyé ní sáà ìṣèjọba alágbádá yìí.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àmọ́ṣá ìgbésẹ̀ náà foríṣánpọ́n, onírúurú ìdí làwọn lámẹ̀tọ́ ìlú ti là kalẹ̀ fún ìjákulẹ̀ náà.

Ìdí àkọ́kọ́: Ọ̀ṣèlú wà nídìí ọ̀rọ̀ náà.

Image copyright @dino_melaye
Àkọlé àwòrán Yahaya Bello àti Dino Melaye ti di ọ̀tá tí wọ́n sì ń sọ pé o ṣeéṣe kó wà lára ohùn tó ṣokùnfà ìgbésẹ̀ ìyọni nípò

Kìí ṣe ìròyìn mọ́ pé àárín Gómìnà ìpínlẹ̀ Kogo, Yahaya Bello àti Dino Melaye kò gún èyí tí wọ́n sì ń sọ pé o ṣeéṣe kó wà lára ohùn tó ṣokùnfà ìgbésẹ̀ náà láti ìpìlẹ̀.

Bíótilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀tàlélọ́ọ̀dúnrún orukọ ni wọ́n gbé kalẹ̀ níwájú àjọ INEC ṣùgbọ́n nígbàtí àjọ náà yóò fi wádìí ó dín ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ̀wá ló gege.Eyi ti ó mú kí ọ̀pọ̀ wòye pé o lọ́wọ́ òṣèlú nínú.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Amòfin Malachi Ugwummadu to jẹ́ ààrẹ àjọ ajàfẹ́tọ́ ọmọnìyàn kan ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdí bíi pé ó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí irúfẹ́ ìgbésẹ̀ yìí yóò wáyé.

o ni gbogbo ọna ti sẹnetọ Melaye gba lati bu omi pa ọrọ naa eleyi to jẹ ki o kuro lookan aya ọpọ pẹlu wa lara awọn idi ti ko lee fi so eso aṣeyọri.

Ìdí kejì: Ìbánikẹ́dùn pẹ̀lú Dino

Image copyright @inecnigeria
Àkọlé àwòrán Ará ìlú wòye pé ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé láàárín àwọn ọlọ́pàá àti Dino jẹ́ ìdí kan

Ọ̀pọ̀ òǹwòye ló rí ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé láàárín àwọn ọlọ́pàá àti Dino gẹ́gẹ ́bíi ara ohun tí àwọn èèyàn kan rò tí wọn kò fi dá sí ìgbésẹ náà mọ́.Ọ̀pọ̀ ló báa kẹ́dùn lóríi ìdààmú rẹ̀ naa.

Amofin melaye ni bi awọn ọlọpa ṣe tun dukuku mọ́ Sẹ́nétọ̀ Melaye kun ara ohun ti awọn araalu rẹ fi kọ ẹ̀yìn sii nitori lọ́kàn wọn 'pipe ni wọn fẹ́ pèé wálé kii ṣe lati paa.'

Ìdí kẹ́ta: Ipa ẹgbẹ́ òṣèlú PDP

Image copyright @dino_melaye
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tó takété sí ètò náà kún àìláṣeyọrí ètò náà

Lóòótọ́ Dino Melaye kò sí ní ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, ṣùgbọ́n bí àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ òṣèlú náà ṣe pàṣẹ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú náà kò gbọdọ̀ kópa nínú ìbò àti yọ sẹnetọ̀ náà lóyè ku ara ohun to pagidínà rẹ̀.

Ẹgbẹ oṣelu PDP ni 'nitori pe Dino n ṣe atilẹyin fun awọn aṣiwaju ileegbimọ aṣofin ti wọn n tako igbesẹ familete n tutọ ijọba APC ni wọn fi n dana iyọkuro nipo fun un.'Ìdí kẹ́rin: Ìdẹ́yẹsí aráàlú.

Image copyright @inecnigeria
Àkọlé àwòrán Ìhà kòkànmí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àwùjọ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà ń kọ sí ọ̀rọ̀ òṣèlú kò jẹ́ kí ètò náà yọrí

Ọ̀kan pàtàkì míràn nínú ohun tó pagidínà ìgbésẹ̀ ọ̀hún ni ìhà kòkànmí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àwùjọ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà ń kọ sí ọ̀rọ̀ òṣèlú àti ìṣèjọba nítorí àwọn ìjákulẹ̀ àtẹ̀yìnwá.

Lóòótọ́, lẹ́yìn ti àyẹ̀wò náà parí, ìwọ̀nba ìdá márùn ún nínú ọgọ́ọ̀rún lo fọwọ́síi.

"ohun jijẹ, mimu, ati ọna ti igbe aye yoo fi rọrun ni pupọ eeyan ipinlẹ Kogi n wa, nitorinaa, [pupọ wọn ni ko raaye gbogbo oni ayẹwo orukọ kan de.

Kini INEC sọ?

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, alákóso fún ètò Idanilekoo awọn olùdìbò lájọ INEC, Deji Shoyebi ni pataki ẹkọ lati inu igbesẹ naa, bi o tilẹ jẹ wi pe o foriṣanpọn ni pe, 'o jẹ́ ki awọn eeyan mọ nipa abala iwe ofin yii ninu iwe ofin Naijiria, bẹ́ẹ̀ni o fi anfani silẹ lati dan abala naa wo niwaju awọn mọ orilẹ̀èdè yii.'

Bakanna lo ni, 'pupọ awọn ti orukọ wọn jade fun eto naa ni ko tilẹ mọ ohun ti wọn tori buwọlu iwe naa lati ìbẹ̀rẹ̀ pẹpẹ.'