Ààrẹ Akufo: Òfin kò fààyè gba ìbálòpọ̀ akọ ṣákọ ni Ghana

Ààrẹ Akufo-Addo àti Theresa May Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ó ní ìgbéyàwó láàárín akọ àti akọ tàbí abo àti abo si lòdì sí òfin lórílẹ̀-èdè Ghana.

Pẹ̀lú onírúurú ìfúngunmọ́ tí orílẹ̀ede Ghana ń kojú, ààrẹ Akufo-Addo ti korò ojú sí ìbálòpọ̀ akọ ṣákọ tàbí abo sábo.

Ààrẹ Akufo-Addo sọ pé Òun kò ní sati lẹ́yìn òfin fún ìbálòpọ̀ láàárín akọ ṣákọ tàbí abo sábo lásìkò ìṣèjọba òun.Ààrẹ Akufo-Addo sọ̀rọ̀ yìí nínú àtejáde kan, Ó ní ìjọba òun ń kojú ìfúngunmọ́ láti sọ ìhà tí òun fì sí láti ìgbà tí Theresa May, olórí ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì tí gorí alefa.Ó ṣàlàyé pé May sọ pé àwọn yóò rán orile-ede lábẹ́ Commonwealth lọwọ láti fi ààyè gba ètò ìgbéyàwó ọkùnrin ṣókùnkùn àti obìnrin sobinrin nínú ìwé òfin orile-ede kòwá wọn tó setan láti fàyè gbà á.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àtẹ̀jáde ọ̀hún wáyé látàrí awuyewuye kan láti ọ̀dọ̀ àwọn alátakò pé ààrẹ Akufo tí fọwọ́ sì òfin náà lórílẹ̀èdè Ghana.Gẹ́gẹ́ bí ààrẹ ṣe sọ, mímú idagbasoke ba awon ara ìlú ni ó jé ìjọba lógún lásìkò yìí.Ó ní ìgbéyàwó láàárín akọ àti akọ tàbí abo àti abo si lòdì sí òfin lórílẹ̀-èdè Ghana.Akufo-Addo ni Ààrẹ ẹlẹ́keeta tí to sọ ní gbangba pé òun kò fọwọ́sí ibalopo ọkùnrin sí ọkùnrin tàbí obìnrin sí obìnrin.