Aàrẹ Trump bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ pẹ̀lú àbò orílẹ̀èdè Nàìjíríà

Àarẹ Donald Trump àti ààrẹ Muhammadu Buhari
Àkọlé àwòrán Aàrẹ Trump bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ pẹ̀lú àbò orílẹ̀èdè Nàìjíríà

Àarẹ Donald Trump ti orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà níbi ìpàdé rẹ̀ pẹ̀lú ààrẹ Muhammadu Buhari sọ àwọn ọ̀rọ̀ àrà ọ̀tọ̀ nípa orílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Ó sọ èyí níwájú ààrẹ Muhammadu Buhari...

"Ìsoro pàtàkì kan wà lórílẹ̀èdè Nàìjíríà pẹ̀lú bí wọ́n se ńpa àwọn krìstẹ́nì - a ó sì sísẹ́ takuntakun lórí èyí nítorí a kò le gbà kí ó sẹlẹ̀".

Bákan náà, ààrẹ Trump mẹnu ba ọ̀rọ̀ àbò nípa ibi ti orílẹ̀èdè Nàìjíríà bá 'sẹ́ dé àti ohun tókù láti se.

A ó máa mú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn yìí wá fún yìn bí ó bá se ńlọ.