Kílódé t'íjọba kò ṣe tíì pe àwọn darandaran ní agbésùmọ̀mí?

awon màálù Image copyright Huw Evans picture agency
Àkọlé àwòrán Ó yẹ ki ìjọba àpapọ̀ ti kede àwọn darandaran gẹ́gẹ́ bíi ẹgbẹ́ adúnkookò-mọ́ni

Pẹ̀lú awuyewuye tó gbòde kan pé kí ìjọba àpapọ̀ kéde àwọn darandaran bí ẹgbẹ́ adúnkookò-mọ́ni

Àwọn ọmọ orile-ede Nàìjíríà tí ń bèèrè pé kinni ìdí tí ìjọba kò ṣe tii ṣe bẹ́ẹ̀ disinyii.BBC Yoruba ṣèwádìí lórí àwọn ohun tó yẹ ka fojú sùn kí a tó lé pè wọn ní agbésùmọ̀mí

Àwọn kan ṣàlàyé àwọn ìdí tí ìjọba kò ṣe tíì lè kéde wọn nígbà tí àwọn mìíràn sọ pé ọ̀rọ̀ òṣèlú ni kò tíì je ki a kéde wọn gẹ́gẹ́ bíi agbésùmọ̀mí.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionkíni ìdí tí ìjọba kò ṣe tíì pe àwọn darandaran ní agbésùmọ̀mi

Ọgagunfeyinti Michael Abiodun Oladeji, tó jẹ́ onímọ̀ nípa eto ààbò, ṣàlàyé pé àwọn darandaran yàtọ̀ sí àwọn Boko Haram àti Niger Delta nítorí pé kò sí ìdí kan pàtó tí wọn fi ń pànìyàn ṣùgbọ́n àìgbọ-ara-ẹni-yé lo ṣokùnfà ìjà àwọn darandaran.

Wọn ní o se pàtàkì fún àwọn eleto ààbò láti mójú tó àwọn tó wà leyin gbogbo ìwà ìpànìyàn tó ń lọ jákèjádò orile-ede Naijiria.

Ní ti Amofin Suleiman Abaya, ó ṣàlàyé pé, ní ìlànà òfin, ìlànà tí wà pé àwọn tó bá dúró gẹ́gẹ́ bí ìpayà fún àwùjọ tàbí tó máa ń pá ènìyàn lai-nìdí, ó di dandan kí ìjọba polongo wọn gẹ́gẹ́ bii agbesumomi ṣùgbọ́n ó dàbí ẹni pé Ìjọba tó ń bẹ lóde tí kọ̀rọ̀ òṣèlú bọ̀ọ̀.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionkíni ìdí tí ìjọba kò ṣe tíì pe àwọn darandaran ní agbésùmọ̀mi

Kíni òfin sọ nípa kikede ẹgbẹ́ kan gẹ́gẹ́ bíi agbésùmọ̀mí

Ẹgbẹ́ to bá ń dúnkookò mo ìjọba láti gba ẹtọ kan

Àwọn egbe tó ní ohun ìjà bíi ìbon, àdó olóró lọ́wọ́

Ìwa ijinigbe àti igbeni-pamọ

Bíba nkan ìní ìjọba jẹ́

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: