Dókítà Trump: Trump ló kọ èsì ìlera rẹ̀ lásìkò ìbò

Aworan Donald Trump Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Ọdun 2015 ni wọn se ayẹwo oni wakati mẹta fun Aarẹ Donald Trump

Dokita Aarẹ Donald Trump ti ilẹ Amerika ti sọ wi pe, oun kọ loun kọ lẹta to juwe ilera ara Trump lọdun 2015, gẹgẹbi ilera to peye ti ko ni abuku.

Dokita naa, Harold Bornstein sọ fun ile isẹ iroyin CNN, ni Ọjọ Isẹgun wipe, Trump funra rẹ lo sọ awọn ọrọ ti awọn kọ si inu iwe ilera rẹ naa.

Bornstein ni, awọn ẹ̀sọ́ Trump yabo ile isẹ oun lọdun to kọja, lati palẹ gbogbo iwe ilera Aarẹ Trump to wa ni ipamọ oun mọ nilẹ..

Amọ, ko ye ẹnikẹni idi ti dokita naa fi jade lati sọ eyi, ati wipe ile isẹ aarẹ, White House ko tii fesi si ọrọ ti dokita naa sọ.

Ti a ko ba gbagbe, ni Osu Kinni, ọdun 2018 ni wọn se ayẹwo oni wakati mẹta fun Aarẹ Donald Trump lati wo bi ọpọlọ re se pe si.