Dino Melaye tún ti wà lagọ́ ọlọ́pàá lẹ́ẹ̀kejì lónì

Dino Melaye Image copyright @dinomelaye
Àkọlé àwòrán Wọn fi ẹ̀sùn kan Dino pé ó jẹ́ bàbá ìsàlẹ̀ f'áwọn adigunjalè

Ìròyìn to tẹ ilẹ̀ ìṣe BBC Yorùbá lọ́wọ́ tẹ́lẹ̀ lórí aṣojú sofin fún ẹkún Kogi West, Senato Dino Melaye, ni pé àwọn ọlọ́pàá yóò fi ọkọ òfuurufú gbé e lọ sí Lokoja loni.

Ṣugbon, ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ, nigba ti olùrànlọ́wọ́ fún sẹ́nátọ̀ Dino Melaye lórí ibanisoro, Gideon Ayodele, fi tó wà leti pé wọn ti fi ẹ̀sùn miran kan Dino.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn gbófinró ń gbé Dino Melaye lọ sí Lokoja

Awon agbofinro ni pé ó jẹ́ bàbá ìsàlẹ̀ fáwọn adigun jalè kan tí owo sìnkún àwọn ọlọ́pàá tẹ̀ ní oṣù díẹ̀ sẹ́yìn.

Nínú iforowanilenuwo pẹlu Gideon Ayodele, lo ti ṣàlàyé pé wọn ti gbé Dino lọ sile ẹjọ́ gíga kan n'ilu Abuja lósàn òní tí adájọ àgbà Abdul Kafarati gba láti gba onídùúró fún un pẹ̀lú àádọ̀rún miliọnu náírà.

Ayodele ṣàlàyé pé àwọn ọlọ́pàá ti tún Dino gbé ní kété tó jáde nílé ẹjọ́ tí wọn sì ń pinnu lati gbé e lọ sí Lokoja. Akitiyan wá láti bá agbenusọ àwọn ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ forí sanpọn nigba ti ẹni tó gbé ero ìléwọ́ rẹ sọ pé ó wà nínú ìpàdé.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: