Bàbá ọgọ́ta ọdún kan pa ara rẹ̀ nílé ìwòsàn UCH Ibadan

Àwòran okunrin naa ninu agbara ẹjẹ rẹ
Àkọlé àwòrán Àgbàlagbà bẹ́ sílẹ̀ láti orí àjà kárùn-ún ní University College Hospital nilu Ibadan

Daru-dapo bẹ silẹ ni Ilé ìwòsàn ìkọ́ni tí Ìlú Ìbàdàn nígbà tí ọkùnrin kan tí ọjọ́ orí rẹ tó ọgọ́ta ọdún gba èmi ara rẹ.

Ìròyìn fi tó wà létí pé ọkùnrin náà bẹ́ silẹ láti orí òkè alaja márùn-ún nínú ilé ìwòsàn náà.

Agbenuso fún àjọ ọlọ́pàá ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ayodeji Bọbade,tó bá akoroyin BBC Yoruba sọ̀rọ̀ fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé àwòrán Orí òkè tí ọkùnrin náà ti bẹ́ sílẹ̀, bàtà rẹ̀, ìwé àkọsílẹ̀ ikú àti owo rẹ̀ ni wọn rí
Àkọlé àwòrán Bàtà ti olóògbé bọ sílẹ̀

Ayẹwo fi hàn pé ọkùnrin náà kò ìwé ikú sapo kí ó tó yọ́ gùn orí òkè tó ti bẹ́ sì ìsàlẹ̀.