Bukọla Saraki; Kò jọwá lójú, ọ̀gá àgbà Ọlọ́pàá ma ń kọ isẹ́ fún ààrẹ

Ile Asofin Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aarẹ Ile Asofin, Bukola Asofin sọwipe kọ jọ oun loju nitori Ọga ọlọpaa naa ti kọ ohun si aarẹ orilẹede Naijiria ri

Ọrọ di wo mi n wo ọ ni Ile Igbimọ Asofin Agba nigba ti Ọga Agba patapata fun ile -ise ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Ibrahim Idris kọ lati yọju si awọn asofin ni Ile Igbimo Asofin.

Iroyin sọwipe igbakeji rẹ laarin ọsẹ meji nìyìí ti Idris ti kuna lati jẹ ipe awọn asofin lori fifi panpẹ ọba mu asofin to n soju ẹkun Kogi, Dino Melaye ati isekupani to n waye kaakiri orilẹede Naijiria.

Ọga ọlọpaa naa lọse to kọja ran igbakeji rẹ, Joshak Habila lati soju fun un nílé Asofin.

Ninu ọrọ rẹ, Aarẹ Ile Asofin, Bukola Asofin sọwipe kọ jọ oun loju nitori Ọga ọlọpaa naa ti kọ ohun si aarẹ orilẹede Naijiria, nigba ti Aarẹ Buhari sọ fun un wipe ko ko ẹru rẹ lọ si Ìpínlẹ̀ Benue lati le bojuto isekupani to n waye lọpọ igba ni agbeegbe naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìgbà kèjì nìyí tí Ílé Ìgbìmọ̀ Asófin Agbà yóò pe Ọ̀gá Ọlọ́pàá láti wá sọ̀rọ̀ lórí ìsekúpani ti Benue

Saraki ni Ọga ọlọpaa naa ko se bi Aarẹ se dari rẹ lọpọ igba, o si fikun un wipe awọn o tii ri i ki ọga ọlọpaa kọ lati yọju si awọn asofin lati igba ti ijọba tiwantiwa ti bẹrẹ lorilẹede Naijiria.

Awọn asofin naa wa pinu lati ran ikọ lọ si ile isẹ aarẹ lati fi aidunnu wọn han lori iwa ti ọga ọlọpa hu si awọn asofin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Ọpẹ́lọpẹ́ Ìbàdàn lára Yorùbá'