Ìkọ̀lù àwọn jàǹdùkú àti fijilanté pa ènìyàn 13 nì Zamfara

maapu Zamfara
Àkọlé àwòrán,

Àarẹ Muhamadu Buhari se àbẹ̀wò sí ágbèègbè náà laipe yii

Ile isẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Zamfara ni o kere tan eniyan mẹtala lo ti padanu ẹmi wọn ti ọpọlọpọ si fara pa ninu ikọlu to waye laarin awọn fijilanté ati awọn janduku ni Zamfara.

Awọn ara ilu ni ikọlu naa waye nigba ti awọn ọde dina awọn aji maalu gbe, ti wọn fẹ gbiyanju ati yabo abule Pankashi ni Zamfara.

Asoju ile isẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Zamfara sọfun ikọ̀ iroyin BBC pe awọn eleto aabo ti wa ni agbeegbe naa, ati wipe alaafia ti pada si agbegbe ọ̀hun.

Ọgọọrọ eniyan lo ti ku ninu ikọlu saaju asiko yi nipinle Zamfara.

Ọpọ ninu wọn lo si sẹlẹ lataari bi awọn janduku to n jii maalu gbe se doju le agbegbe naa.

Eyi si mu ki awọn fijilanté lagbegbe wa ọna lati le koju awọn janduku naa.