Wọ́n jí òsìsẹ́ ẹgbẹ́ alágbèlébù pupa gbé ní ìlú Mogadishu

àmì ìdámọ̀ ẹgbẹ́ alágbèlébù pupa Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Wọ́n jí òsìsẹ́ ẹgbẹ́ alágbèlébù pupa gbé ní ìlú Mogadishu

Ẹgbẹ́ alágbèlébù pupa lágbayé, ICRC ní wọ́n ti jí ọ̀kan lára àwọn òsìsẹ́ rẹ̀ gbé ní Mogadishu tíí se olú ìlú Somalia. Àwọn agbébọn jí nọ́ọ̀sì ará Germany yìí gbé ní ọgbà ilé isẹ́ ẹgbẹ́ alágbèlébù pupa lálẹ́ ọjọ́rú ọ̀sẹ̀.

Ìsẹ̀lẹ̀ náà wáyé ní ǹkan bí ago mẹ́jọ alẹ́ ọjọ́rú ọ̀sẹ̀ èyí tó jẹ́ àfikún ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbọ́nmi síi omi ò tó tó ti sọ orílẹ̀èdè Somalia di ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀èdè tó léwu fún àwọn olùtọ́tú aláìsàn láti sisẹ́.

Akọ̀ròyìn BBC Africa, Tomi Oladipo jábọ̀ pé àwọn olùgbé Mogadishu níbi tí wọ́n ti jí nọ́ọ̀sì ọ̀hún gbe sọ wípé lẹ́yìn tí ìsẹ̀lẹ̀ náà làwọn òsìsẹ́ aláàbò ti kalẹ̀ síbẹ̀.

Ẹgbẹ́ alágbèlébù pupa ní ìsẹ̀lẹ̀ náà ká wọn lára bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n ní ìmọ̀lára rẹ̀. Wọ́n sàpèjúwe nọ́ọ̀sì náà gẹ́gẹ́ bí ẹni tó máa ńsisẹ́ lójoojúmọ́ láti mú ìgbega bá ìlera àwọn ara Somalia.

Ko sí ohun tó tanilólobó ẹni tó jí i gbé sùgbọ́n ẹgbẹ́ ICRC ní àwọn ńsisẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tọ́rọ̀ kàn láti ríi pé wọ́n tú u sílẹ̀

Ìsẹ̀lẹ̀ ìjínigbé yìí wáyé lẹ́yìn ọjọ́ kan tí àwọn agbébọn pa òsìsẹ́ àjọ elétò ìlera lágbayé, WHO láì mọ̀'dí ìsẹ̀lẹ̀ náà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: