Alex Iwobi: Ó dùn mí pe Arsene Wenger ń lọ

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAlex Iwobi: Ó dùn mí pe Arsene Wenger ń lọ

Alex Iwobi fìmoore hàn sí Arsene Wenger lórí ìrànlọ́wọ́ tó ṣe fún un

Akọ́nimọ̀ọ́gbá àgbà, Arsene Wenger, ń kùró ní ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Arsenal, lẹ́yìn ọdún méjìlélógún tó tí wà pẹ̀lú wọn.

Alex Iwobi, to jẹ́ ọmọ Naijiria to n gba bọ́ọ̀lù fun Arsenal ní lilọ Wenger dun oun ṣugbọn yoo tun jẹ́ kóríyá sìṣẹ́ fun oun.

Arsene Wenger ràn mí lọ́wọ́ púpọ̀.

Image copyright @twitteralexiwobi
Àkọlé àwòrán Arsene Wenger ràn mí lọ́wọ́ púpọ̀ nínú ìlósíwájú iṣẹ́ mi

O fi ìbẹ̀rù àìmọ akọ́nimọ̀ọ́gbá ti yoo gba ipò Wenger hàn pẹlu ipinnu pé ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Arsenal yoo sa ipá wọn lati fun Wenger ni ẹbun jijawe olubori ninu idije ki inu rẹ̀ lè dùn.

Gunners àti Atletico Madrid gbá ọ̀mì (1-) nibẹ̀rẹ̀ idije ni Emirates. Iwobi gba pe awon yoo na Atletico Madrid mọ́lé.

Ko si ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó tíì na Atletico Madrid ninu idije Wanda Metropolitano ni sáà LaLiga yii

Ọjọ́ kerindinlogun, oṣù karun un ni wọn maa gba àṣekágbá Europa League ni Lyon.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAlex Iwobi: Ó dùn mí pe Arsene Wenger ń lọ