Pufferfish - NAFDAC kígbe síta lórí ẹja aṣekúpani tó wà nígboro

Ẹja Puffer

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Gẹgẹ bii ajọ NAFDAC ṣe sọ ninu awọn ẹya ara ẹja naa bii ẹdọ, ifun ati awọ ara rẹ ni awọn majele fara sinko si

Bi o ba ri ẹja kan lọja eleyi ti wọn n pe orukọ rẹ ni 'Pufferfish' tete yara sa asala fun ẹmi rẹ.

Ajọ to n gbogun ti ilokulo ounjẹ, ohun mimu ati ogun lorilẹede Naijiria, NAFDAC lo ṣe ikilọ yii ni ọjọ ẹti.

Lati orilẹede Japan, China ati Korea ni ajọ NAFDAC ni ẹja yii ti n wa si orilẹede orilẹede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Bi eeyan se ẹja yii tabi koo pamọ sinu ẹrọ amohuntutu, kaka ki majele ara rẹ parẹ, n ṣe ni yoo maa rin kaakiri agọ ara rẹ

"Ẹja yii ni majele kan ni ara rẹ eleyi to lee ṣakoba fun ẹnikẹni to ba jẹ ẹ. Aisan ni yoo ko ba ẹni bẹẹ eleyii ti o si lee ja si iku fun un."

Gẹgẹ bii ajọ NAFDAC ṣe sọ ninu awọn ẹya ara ẹja naa bii ẹdọ, ifun ati awọ ara rẹ ni awọn majele fara sinko si.

Ko si ohun ti a lee ṣe lati fi yọ majele yii kuro lara ẹjọ yii-boya sise e tabi kikoo pamọ sinu ẹrọ amohun tutu ko ran an.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Lati orilẹede Japan, China ati Korea ni ajọ NAFDAC ni ẹja yii ti n wa si orilẹede orilẹede Naijiria

Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, bi eeyan se ẹja yii tabi koo pamọ sinu ẹrọ amohuntutu, kaka ki majele ara rẹ parẹ, n ṣe ni yoo maa rin kaakiri agọ ara rẹ.

Nibayii, ajọ NAFDAC ti pariwo sita lori ẹja yii ati ọṣẹ ti o n ṣe lagọ ara ti wọn si ti kilọ f'awọn onile ounjẹ gbogbo ati oniṣowo ẹja lati maṣe ta ẹja yii fun ẹnikẹni nitori ọta ilera ni.

NAFDAC: A ń se ìwádìí pínpín oògùn ikọ́ Coedine délẹ̀

Oríṣun àwòrán, @nafdactwitter

Àkọlé àwòrán,

NAFDAC ti ṣetan láti wádìí àwọn ilé iṣẹ́ apoògùn fínnífínní lórí ọ̀rọ̀ coedine

Fídíò Coedine BBC ṣí ojú NAFDAC sí iṣẹ́ ìwádìí tó yé kí wọ́n ṣe

Ní kété tí BBC ti gbé fídíò àwón ọ̀dọ́ ti wọ́n n mu òògùn ikọ́ olómi Coedine síta ní ó ti n so èso rere fún iṣẹ́ ìwádìí àti òfin ìlera túntún.

Bayii, ìjóba Naijiria ti fi ofin de lilo Coedine ati Tramadol ninu òògùn ikọ́ pípò.

Ile igbimo aṣofin agba ni Abuja naa ti sọ̀rọ̀ lori koko yii.

Aya aare, Aisha Buhari atawon èèkàn kaakiri Naijiria ti bẹ̀rẹ̀ ifowosopọ̀ lori gbigbogun ti iwa ibaje yii.

Lọ́wọ́lọ́wọ́, awon ile ise ijoba apapo ni Naijiria to n mojuto gbigbogunti àṣìlò ohun jijẹ ati oogun lilo, NAFDAC, ti kede pe wọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí nínú awọn ilé isẹ́ mẹ́rẹẹrin ti Fídíò BBC menuba.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Mojisola Adeyeye, to je oludari ajọ NAFDAC, ni "A o gbé igbesé to ba yẹ ni kete ti a ba pari ìwádìí nínú awọn ile ise mereerin ti Fídíò BBC tú síta".

O ṣeleri pe ìyà tótọ́ nijoba yoo fi jẹ ile iṣẹ to ba lùgbàdì òfin ìlera.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Àìsàn ibà; Àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nípa lílo ewé áti egbò