Mílíọ̀nù Márùn-ún ènìyàn n bẹ nínú ewu ìyàn

Aworan ọmọdé ti ebi ń pa Image copyright STEFAN HEUNIS/AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ tó dín díẹ̀ ni mílíọ̀nù méjì ń gbé nínú aìjẹun-kanu

Ówọ́n gógó oúnjẹ, ọ̀gbẹlẹ̀ àti rògbòdìyàn tí lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sínú ebi àti ìyàn.

Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ tó dín díẹ̀ ni mílíọ̀nù méjì ń gbé nínú aìjẹun-kanu làwọn agbègbè ìwọ oòrùn ilẹ̀ Áfíríkà.Àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé (UN) lo kéde ọ̀rọ̀ òhún lónìí, pẹlu alaye pé, tí àwọn orílẹ̀ èdè ó bá wà ojútùú sí ìṣòro náà afaimo ni kí nkan má bajẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àjọ àgbáyé (UN) lo kéde pé ó ṣe pàtàkì láti wá ojúùtú sí ọ̀rọ̀ àìtó o

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àjọ àgbáyé to ń rí sì ọ̀rọ̀ ohun ogbin, àti Oúnjẹ sọ pé ojo ti ko ro daradara làwọn agbègbè Senegal, Mali, Niger, Burkina Faso àti orile-ede Chad lọ́dún tó kọjá lọ ṣokùnfà ohun tó ń dá igbayegbadun àwọn ènìyàn tó sì ṣokùnfà ìyàn lásìkò yìí.

Image copyright STEFAN HEUNIS STEFAN HEUNIS/AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọmọ tó dín díẹ̀ ni Mílíọ̀nù méjì ni ó wà nínú ewu àìrí oúnjẹ jẹ

Ó kéré tán ènìyàn tó lé ní Mílíọ̀nù Márùn-ún ni yóò nílò oúnjẹ àti iranlọwọ láti gbé ìgbé ayé wọn lásìkò tó ṣeé ṣe kí nkan burú sii.

Onímọ̀ nípa ọ̀rọ̀ oúnjẹ, Cadre Harmonise, sọ èyí di mímọ̀ nínú àtejáde kan pé yóò ṣélẹ̀ bíi ọdún mẹ́rin sì àsìkò yìí. Ó ní jákèjádò orílẹ̀-èdè mẹ́fà pẹ̀lú ní ọmọ tó dín díẹ̀ ni mílíọ̀nù méjì ni ó wà nínú ewu àìrí oúnjẹ jẹ.