Afanso Dhlakama, olórí alátakò ìjọba Mozambique fayé sílẹ̀

Àwòrán Afanso Dhlakama Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àrùn ọkàn ló pa Afanso Dhlakama léni ọdún márùnlélọ́gọ́ta

Olórí àwọn alátakò ìjọba to pé julọ lórílẹ̀-èdè Mozambique Afonso Dhlakama tí fáyé silẹ lónìí.

Afonso kú nítorí àrùn ọkàn léni ọdún marunlelogota.Ó jẹ́ adarí ẹgbẹ́ òṣèlú Renamo lásìkò isọ̀tẹ̀ sí ìjọba Mozambique fún ọdún márùn-úndinlogun to dópin lọ́dún 1992.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ìjọba aláwọ̀ funfun orile-ede South Africa ló jẹ́ alátilẹ́yìn fún ẹgbẹ́ wọn.Wọn fi ẹ̀sùn Ipànìyàn, ṣíṣe àwọn ènìyàn básubàsu àti lílo àwọn ọmọ kéékèèké fún ìṣe ogún kan Renamo.Lẹ́yìn tí ogún abele pari ni Renamo di adarí ẹgbẹ́ alátakò ìjọba orile-ede Mozambique.Títi di àsìkò yìí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ sì ń dójú ìjà kọ àwọn ọmọ ogun ìjọba orile-ede Mozambique.