Fídíò BBC ń fa gbùrù, gbùrù ń fa igbó ilé iṣẹ́ apoògùn

Atóka ile iṣe apoògùn Bioraj
Àkọlé àwòrán Òkan lára àwọn ilé iṣẹ́ ti Fídíò BBC mẹ́nubà

Ilé iṣẹ́ apoògùn Bioraj ni Ilọrin, ìpínlẹ̀ Kwara ti dá Baba Ibeji dúró

Bí fídíò BBC lórí oògùn ikọ́ olómi ṣe ń gbilẹ̀ síi ni ó ń fa gbùrù fún ilé iṣẹ́ apoògùn àti ìjọba, bẹ́ẹ̀ náà ni gbùrù àwọn ilé iṣẹ́ apoògùn tí ń fa igbó àwọn òṣìṣẹ́ wọn

Ile iṣẹ́ apoògùn Emzor ló kọ́kọ́ da òṣìṣẹ́ rẹ́ ti igbá ìwà ìbàjẹ́ yìí ṣi mọ́ lọ́wọ́ dúró.

Bayii, ile iṣẹ́ apoògùn Bioraj naa ti fi atẹjade sita pe oun ti ni ki Ogbeni Junaid Hassan ti gbogbo eniyan n pe ni Baba Ibeji lọ rọọ́kún nílé ná.

Arakunrin yii ni o ta oògùn ikọ́ olómi oní coedine fun ikọ̀ BBC to wa ṣiṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ to tu sita naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

BBC lo gbe fidio ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ kan jade ti o fi ṣàfihàn ewu ńlá to wa ninu mímu àpọ̀jù iru oògùn ikọ́ báyìí ni Naijiria.