Ilé Asòfin yóò buwọ́ lu àbá ìsuna ọdún 2018 lọ́sẹ̀ tó mbọ̀

Ilé ìgbìmọ̀ asojúsòfin Nàìjíríà Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ilé Asòfin yóò buwọ́ lu àbá ìsuna ọdún 2018

Ilé ìgbìmọ̀ asojúsòfin orílẹ̀èdè Nàìjíríà ti sọ wí pé awọn yóò gba àbá ètò ìsúná ọdún 2018 wọlé lọ́sẹ̀ tó mbọ̀.

Agbẹnusọ fún ilé ìgbìmọ̀ asojúsòfin, Abdulrazak Namdas ló kéde èyí lẹ́yìn ìpàdé ilé nígbà tó mbá àwọn oníròyín sọ̀rọ̀.

Namidas ní wọn yóò gbé àbádòfin náà síwájú àwọn asòfin ní Ọjọ́ Àìkú ọ̀sẹ̀, tí wọn yóò sì gbàá wọle láàrin ọ̀sẹ̀ kan náa.

Ó fi kún un wípé lọ́sẹ̀ tó mbọ̀ yìí kan náà ni ohun gbogbo tó ní se pẹ̀lú àbá ètò ìsúná yóò di síse

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sáájú èyí, ìròyìn fi tó ni létí wipe àwọn akọ́sẹ́mọsẹ́ nínú ètò ìsùná ti fi àìdunú hàn lórí bí ilé asòfin se dá bíbọwọ́lu àbádòfin náà dúró.

Related Topics