Ajurawalọ......Ìjàkadì kọ́?

Tony Bellew n na David Haye Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Tony Bellew ṣíná fún David Haye

Bellew fi han Haye pé ọgbọ́n ju agbára lọ ni ọ̀rọ̀ ìjàkàdì

Gbájugbajà akànṣẹ́ kù bi òjò, Bellew Tony, tó jẹ́ ọmọ ọdún marundinlogoji ti na David Haye, to jẹ́ ọmọ ọdún mẹtadinlogoji.

Ilu London ni ìdíje náà ti wáyé nibi ti Ballew kò ti náání pé Haye ju òun lọ ni ọjọ́ orí àti ni ìwọn bi ó ṣe wúwo tó.

Ẹẹ̀kejì rè e ti àwọn mejeeji má a pàdé

Ipele karun un ìjà náà ló ti jáwé olúborí, lọ ba fayọ̀ gbé àmì ẹyẹ lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Tony Bellew ni ó ṣeéṣe pé ti òun kò ba pàdé ẹni tó tó ajanaku, tó kọja mo rí ǹkan fìrí, òun kò ni jà mọ́