Lagos: Ọba Ayangbure ti ìlú Ìkòròdú pàsẹ k'áwọn obìnrin gbélé

Àwòrán ojú ọ̀nà tó dá páro páro Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọba Ayangbure ti ìlú Ìkòròdú pàsẹ k'áwọn obìnrin gbélé

Lórí ọ̀rọ̀ pé wọ́n kéde ìgbélé f'áwọn obìnrin tó ń gbé ní Ìkòròdú láti má jáde lọ́jọ́ kẹjọ osù kárùn-ún torí pé orò fẹ́ jáde, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ti ń fèsì lórí ojú òpó Facebook BBC Yoruba.

Ní agbegbe Ìkòròdú ní Ìpínlẹ̀ Èkó, wọ́n ti kìlọ̀ pé kí àwọn obìnrin gbélé ní ọjọ kẹjọ osù kárùn-ún tíí se ọdún Magbo nítorí wípé orò yóò jáde.

Ọba Kabiru Shotibi tó jẹ́ Ayangbure ti ìlú Ìkòròdú sọ wípé àsà ilẹ̀ kọ̀ ọ́ kí àwọn obìnrin tẹ ìta tàbí rìn káàkiri ìlu ní ọjọ́ yìí tí ó pè ní ọjọ́ Orò.

Image copyright @chidiodinkalu
Àkọlé àwòrán Orò ní Ìkòròdú yóò gbé obìnrin tó bá jáde

Nínú lẹ́tà kan tí wọ́n kọ jáde, wọ́n kìlọ̀ wípé kí àwọn ènìyàn gbọ́ ìkìlọ̀ yékéyéké.

Lára àwọn èsì tí wọ́n fọ̀ nìyìí:

Àkọlé àwòrán Èsì àwọn ènìyàn lórí pé wọ́n kéde ìgbélé f'áwọn obìnrin ní Ìkòròdú torí orò
Àkọlé àwòrán Èsì àwọn ènìyàn lórí pé wọ́n kéde ìgbélé f'áwọn obìnrin ní Ìkòròdú torí orò

Lẹ́tà náà tí wọ́n kọ l'édè gẹ̀ẹ̀sì kà báyìí:

"Èyí ni láti fi tó o yín létí nípa ọdún tí yóò wáyé ní ọjọ́ ìsẹ́gun, ọjọ́ kẹjọ osù kárùn-ún ọdún 2018. Gẹ́gẹ́ bí àsà ìlú, a kò gbudọ̀ rí obìnrin kankan kò jáde tàbí rìn kiri ìlú lọ́jọ́ tí wọ́n dá yìí èyí tó jẹ́ ỌJỌ́ ORÒ"

"A óò mọ rírì ìfọwọ́sowọ́pọ́ yín fún àseyọrí àjọ̀dún yìí" Ẹ se é sáájú àkókò náà ọlọ́run yóò sì bùkún yín."

Ẹ̀wẹ̀, àwọn olùgbé ìlú Ìkòròdú ti fun[pè sí ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó láti f'òpin sí ọdún orò ní agbègbè yìí tàbí kí wọ́n sún un sí òru ọ̀gànjọ́ nítorí wọ́n ní ó máa ń dí kátàkárà àti ètò ẹ̀kọ́ lọ́wọ́.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: