Osinbajo àti PDP ń jiyàn lórí ìkówójẹ́ lábẹ́ àwọn adarí wọn

Yẹmi Osibajo ati Uche Secondus, alaga ẹgbẹ oṣelu PDP Image copyright @ProfOsinbajo/@OfficialPDPNig
Àkọlé àwòrán Bùhárí kò lè fọwọ́ sọ̀yà pé òun kógojá nígbà tí àwọn tó ba ni ẹ̀sùn ìkówòjẹ kìí jẹ́jọ́ mọ́ bí wọ́n bá ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC

Ọ̀rọ̀ ti ń di èyí tí à ń gbà bí ẹni gba igbá ọtí, láàárín igbákejì ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàíjíríà, Yẹmí Osinbajo, ati ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, lórí ìdánimọ̀ ati orúkọ àwọn tó da owó ìlú si àpò arawọn.

Bí igbákejì ààrẹ, Yẹmí Osinbajo, ṣe ń lọgun pe owó tí èèyàn mẹ́ta lábẹ́ ìṣèjọba Aarẹ Goodluck Jonathan gbé lé ní bílíọ̀nù mẹ́ta náírà; bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹgbẹ́ òṣèlú PDP pẹ̀lú ń pariwo pé ọ̀rọ̀ òṣèlú lásán ni wọ́n ń fi ṣe.

Àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ tó bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀ sọ pé irúfẹ́ èyí kò leè ṣàì wáyé bí ìdìbò 2019 ṣe ń súnmọ́ etílé.Àmọ́ ọ̀rọ̀ ìyànjù tí ọ̀pọ̀ gbé kalẹ̀ ni pé àti igun kínií àti ìkejì, aráàlú ń wò wọ́n láti mọ ibi tí wọ́n bá orilẹ-ède yìí de.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ogbẹ́ni Adéníyì Táíwò Kunu, tó jẹ́ òǹwòye nípa ọ̀rọ̀ tó ń lọ láwùjọ ba BBC Yorùbá sọ̀rọ̀.

O ṣalaye pé ohun tó kù díẹ káàtó ni lati máa dárúkọ láì jẹ́ kí aráàlú ri àbájáde gbogbo ariwo orúkọ tí wọ́n ń fi síta.Ọ̀gbéni Kunu ní kò sí àǹfàní nínú dídá orukọ nígbà tí àwọn èèyàn kan tí aráyé mọ̀ pé aṣọ àlà wọn kò mọ́ rọ̀gbà yí ààrẹ Mùhámádù Bùhárí fúnrarẹ̀ ká ."Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé ẹni tó bá ṣẹ̀, a níláti tọ ìlànà àátẹ̀ẹ́lé lábẹ́ òfin.

Irú èèyàn bíi igbákejì ààrẹ to jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ nípa òfin yẹ kó mọ̀ pé nǹkan báyìí kọjá ká máa pariwo orúkọ kiri ."

Image copyright Nigeria Presidency
Àkọlé àwòrán Osinbajo ń lọgunìkówójẹ lábẹ́ ìṣèjọba Jonathan ẹgbẹ́ òṣèlú PDP pẹ̀lú ń pariwo pé ọ̀rọ̀ òṣèlú lásán ni wọ́n ń fi ṣe

Bákannáà ló ní ààrẹ Mùhámádù Bùhárí kò lè fọwọ́ sọ̀yà pé òun kógoja pẹ̀lu bi o ṣe jẹ pé àwọn to ba ni ẹ̀sùn ìkówòjẹ lọ́rùn wọn kìí jẹ́jọ́ mọ́ ní kété tí wọ́n bá ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC.

"Ìjọba Bùhárí gan tó ń sọ̀rọ̀ kò tẹ̀lé ìlànà òfin lórí bàálù tó rà láì gb'àṣẹ; ìwà ìbàjẹ́ lèyí pẹ̀lú".

O ni ṣe ló yẹ káráàlú ó máa dunnú pẹ̀lú bí àwọn alágbára ṣe ń tú àṣírí ara wọn.