Ilẹ́esẹ́ ọlọ́pàá: A kò mọ̀ bóyá wọ́n san owó fáwọn ajínigbé

Ọlọ́pàá Nàìjíríà Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọlọ́pàá dá amojú ẹ̀rọ́ ara Germany sílẹ̀ ní Kano

Wọ́n ti dá amojú ẹ̀rọ ọmọ orílẹ̀èdè Germany tó ń sisẹ́ pẹ̀lú ilé isẹ́ Dantata and Sawoe, tí àwọn ajínigbé jí gbé ní ìpínlẹ̀ Kano sílẹ̀.

Ọjọ́ kẹrìndínlógún osù kẹrin ni wọ́n jí ọ̀gbẹ́ni Michael Cremza gbé sùgbọ́n níwọ̀n ìgbà tí wọ́n ti tú u sílẹ̀, ó ti wà nílé ìwòsàn tí ara rẹ̀ sì ti ń yá.

Alukoro ilé isẹ́ ọlọ́pàá ló sọ èyí fún ilé isẹ́ ìròyìn BBC. Ó ní kò ì tíì yé bóyá wọ́n san owó láti ríi gbà sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé ọ̀hun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ó ní "ohun tí mo mọ̀ ni wí pé ọ̀gbẹ́ni Michael Cremza ti gba ìdáǹdè báyìí ara rẹ̀ sì ti ń yá nílé ìwòsàn. Bẹ́ẹ̀ sì ni ikọ̀ tó se àrídájú ìtúsílẹ̀ rẹ̀ wà lábẹ́ ìdarí kọmísánà ọlọ́pàá ti ẹ̀ka kínní, èyí tí ọ̀gá pátápátá ọlọ́pàá rán.

Osù tó kọjá ni àwọn adigunjalè márùn-ún dà'bọn bo ọkọ̀ tí ó ń gbé amojú ẹ̀rọ náà lọ sí ibi tó ti ń sisẹ́, kódà wọ́n pa ọ́lọ́pàá tó tẹ̀lé e lọ.