Ibà Lassa: Ẹ̀mí òsìsẹ́ ìlera ní Ondo bọ́

Òsìsẹ́ ìlera
Àkọlé àwòrán,

Lassa Fever gba ẹ̀mí òsìsẹ́ ìlera ní Ìpínlẹ̀ Ondo

Òsìsẹ́ ìlera kan ní ìpínlẹ̀ Òndó, Rasheedat Mohammed ti gbẹ́mìí mì látàrí ìkọlù àìsàn ibà Lassa.

Ìròyìn tó ni létí wípé, olóògbé náà dákẹ́ ní ibùdó tí wọ́n ti ń tọ́jú kíndìnrín ní ilé ìwòsàn ti ìpínlẹ̀ Ondo. Wọ́n ní òsìsẹ́ inú yàrá àyẹ̀wò yìí kó àìsàn ibà Lassa náà ní ìlú Porthacourt níbi tó ti lọ se àbẹ̀wò sí mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kan tó ti kó àrùn náà, tó sì ti ba ibẹ̀ lọ.

Láìpẹ́ ni àwọn òsìsẹ́ ilé ìwòsàn náà ké gbàjarè pé àwọ́n alásẹ kò gbé ìgbésẹ̀ láti dá àbò bo àwọn òsìsẹ́.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọ́n alásẹ ilé ìwòsàn náà wí pé, wọ́n mọ̀ nípa ìsẹ̀lẹ̀ àìsàn Lassa nínú ilé ìwòsàn ọ́hún, tí wọ́n sì ti fi tó olùdarí àgbà ilé ìwòsàn létí sùgbọ́n wọ́n ní, ó kọ̀ láti pàsẹ pé kí wọ́n se àyẹ̀wò fún àwọn òsìsẹ́ pàápàá àwọn tó ń rí sí ètò ìlera.

Ní ìdàkejì ẹ̀wẹ̀, Kọmísánà ìpínlẹ̀ náà fún ètò ìlera, Dókítà Wahab Adegbenro sọ pé, kò sí irú ìsẹ̀lẹ̀ yìí ní ìpínlẹ̀ náà.