APC: Idibo abẹle ni Ekiti di Satide

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC ń se ipolongo ita gbangba Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ́ òsèlú APC ṣèlérí láti ṣe àtún-gbéyẹ̀wò ááwọ̀ tó wáyé ní Èkìtì

Ẹgbẹ oselu APC lorilẹede Naijiria ti sun ọjọ idibo abẹle saaju idibo si ipo gomina ni ipinlẹ Ekiti si iwaju.

APC fi ọjọ idibo naa si Ọjọ Ẹti, ọjọ kọkanla tẹlẹ, ko to di wipe wọn wa sun si iwaju di ọjọ Satide, ọjọ kejila, Osu Karun, ọdun 2018.

Adari ipolongo fun ẹgbẹ oselu naa, Bolaji Abdullahi sọ wipe awọn gbe igbese naa, lẹyin ipade laarin awọn adari oselu naa ati awọn oludije si ipo gomina labẹ ẹgbẹ oselu APC naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ti a ko ba gbagbe, ẹgbẹ oselu APC pinnu lati tun idibo abẹle naa se lẹyin ti rogbodiyan suyo nibi idibo akọkọ ti wọn se ni ọsẹ to kọja.