IGP Idris: Mí o lálàyé kankan láti ṣe fún ẹnikẹ́ni

Aworan ọ̀gá ọlọ́pàá Nàìjíríà Image copyright TWITTER/NIGERIA POLICE
Àkọlé àwòrán O tó ọ́jọ́ mẹta ti ọ̀gá ọlọ́pàá ati àwọn aṣòfin ti ń fa ọ̀rọ̀ náà bọ̀

Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá lorílè-èdè Nàìjíríà, Ibrahim Idris, tí fèsì sí ọrọ̀ ilé aṣòfin àgbà tó ṣàpèjúwe rè gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá ìjọba tiwa n tiwa.

Idris ní òun kò ní àlàyé kánkan láti ṣe fún ẹnikẹ́ni.

Moshood Jimoh, tó jẹ́ alukoro iléèsẹ́ ọlọ́pàá lorílè-èdè náà ló fi ọrọ yí lédè nínú atẹjade kàn.

''Idun kúkú lájá moní ati ọgbọn àti gbóná eburu yíká òfin ní wọn n dá.Òfin f'aye gbà kí ọgá ọlọ́pàá rán aṣojú wá tí ilé ba ranṣẹ pè.''

Atẹjade náà ti wọn tun fi si oju opo Twitter wọn fí kún pé iléèsẹ́ ọlọ́pàá kò ní juwọ lẹ fún ẹnikẹ́ni tó bá fẹ tapa sofin ilẹ Nàìjíríà.

Lọ́jọ́ọ̀rú ni ààrẹ ile aṣòfin àgbà Senato Bukola Saraki júwe Idris gẹ́gẹ́ bíi ọ̀tá ìjọba tiwa-n-tiwanigba ti o tún kùnà láti farahàn níwájú ilé.