Obìnrin Nàíjíríà: Ẹ pèsè ààbò àti ìbádọ́gba f‘un wa

Àwọn obìnrin tó ń fẹ̀hónú hàn
Àkọlé àwòrán Àwọn obìnrin ń sàfihàn onírúurú ìwé àkọlé tó wà lọ́wọ́ wọn.

Àwọn obìnrin jákèjádò Nàíjíríà ti ń kóra jọ sí ìlú Àbújá nínú ìwọ́de alágbára kan .

Àwọn obìnrin yìí ni wọ́n fọnmú, tí wọn sì ń bèèrè fún ìbára-dọ́gba pẹ̀lú àwọn ọkùnrin lágbo òsèlú lásìkò ètò òsèlú tó ń bọ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn olùwọ́de náà, tí wọn tú jáde lẹ́gbẹ̀-lẹ́gbẹ̀, ti kóra jọ sí iwájú ilé asòfin àpapọ̀, tí wọn sì ń sàfihàn onírúurú ìwé àkọlé tó wà lọ́wọ́ wọn.

Àkọlé àwòrán A fẹ́ dọ́gba pẹ̀lú ọkùnrin nínú òsèlú

Àwọn àkọlé náà ló ń pè fún ètò ààbò tó péye, ìkópa àwọn obìnrin nínú òsèlú ní ìbára-dọ́gba pẹ̀lú àwọn ọkùnrin.