Ojúdù: Apẹ̀tù sááwọ̀ ni mo fẹ́ jẹ́ ní APC Èkìtì

Babafemi Ojudu ti ẹgbẹ APC Image copyright Babafemi Ojudu/Facebook
Àkọlé àwòrán Asiko to lati dide gẹgẹ bi apẹ̀tù sááwọ̀

Babafemi Ojudu to jẹ ọmọ ẹgbẹ APC, ti bá awọn akọ̀royin sọrọ wipe oun ko dije ipo gomina mọ nipinlẹ Ekiti. O wipe asiko ti to fun oun lati dide gẹgẹ bi apẹ̀tù sááwọ̀ ni ipinlẹ̀ Ekiti.

Siwaju, o wipe oun ti ba awọn agbẹjoro agba, oloye Olanipekun ati Femi Falana sọrọ̀ pe, agba kii wa lọja ki ori ọmọ tuntun o wọ.

O ni oun fẹ ki wọn jọ sowọpọ lati ri pe, ko si ipaniyan tabi rogbodiyan kankan ni akoko idibo ni ipinle Ekiti, ati wipe, ki awọn ri daju wipe awọn jẹgudujẹra ko bọ sori aleefa nipinlẹ Ekiti.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Babafemi Ojudu jẹ okan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ APC mẹtalelọgbọn to kopa ninu idibo abẹle to waye nipinlẹ Ekiti lọse to kọja.