Chef Ken: Epo, ata, irú, pọ̀nmọ́, àlùbọ́sà l'ọ̀rẹ́ ẹ̀fọ́

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẹ̀fọ́ rírò jẹ́ alábárìn iyán, fùfú, ẹ̀bà, àmàlà àti ìrẹsi funfun

Tẹ̀tẹ̀, ṣọkọ, ìgbá, ebòlò, gírìnnì, gbúre, amúnútutù, ewúro, wọ̀rọ̀wọ́ jẹ díẹ̀ nínú oríṣi ẹ̀fọ́ tó wà

Ayokunle Apoẹṣọ, Chef Khen ló se ọbẹ̀ àjẹpọ́nnulá tọsẹ̀ yìí fún BBC Yoùbá.

Àkọlé àwòrán Láìsí epo, rodo, irú, éja, pọ̀ǹmọ́, àti àlùbọ́sà; ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ kò tíì sè

Ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ rírò tó kún fún èròjà amáradàgbà bíi epo pupa, ata rodo, irú (wooro tàbí pẹ̀tẹ̀), éja yíyan, ìgbín, ògúnfe, pọ̀ǹmọ́ Ìjẹ̀bú, àti àlùbọ́sà ni gbajúgbajà alásè náà sè.

Gbogbo ìnáwó bíi ìkómọjáde, òkú àgbà, ìyàwó, ọjọ́ ìbí, oyè jíjẹ́ àti bẹẹ bẹẹ lọ ni Yorùbá ti ń se ẹ̀fọ́ rírò.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌlù jẹ́ ohun èlò fún ìgbésí ayé ọmọ Yorùbá

Àwọn oúnjẹ ti wọn fi ń gbádùn ẹ̀fọ́ rírò ni iyán, fùfú, ẹ̀bà, àmàlà àti ìrẹsi funfun.

Àkọlé àwòrán Ẹfọ rírò, ọbẹ̀ àjẹpọnnula tó kún fún èèlò tó pójú owó

Chef Ken ṣalaye kíkún lori àwọn ìgbésẹ̀ ríro ẹ̀fọ́ tó dùn nínú fídìò yì, ẹyin náà ẹ dán an wò lopin ọ̀sẹ̀ yíì f'awọn ololufẹ yin!