Ajínigbé kan kú, sùgbọ́n àwọn ọlọ́páà ti padà si ilé

Awọn olopaa ni iwaju ile ejo ni eko Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Sájẹ́ntì ọlọ́paàá Haladu Mohammed ati ìkejì rẹ̀ ni wọn ji gbé ní Port Harcourt

Ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ méjì kan ti àwọn ajínígbé gbá mú ní Port Harcourt, Ìpínlẹ̀ Rivers ni ọ̀sẹ̀ tó kọjá ti gba ìdáǹdè bayii.

Agbẹnusọ ọlọpaa ni ipinlẹ naa ni Sájẹ́ntì ọlọ́paàá tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Haladu Mohammed ati ìkejì rẹ̀ tí wọ́n jọ jẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ lati ilé iṣẹ́ ọlọpàá tí ó ń ṣe iwádìí ìwà ọdaran ni Abuja ni wọn jí gbe nígba tí wọn ṣisẹ́ lọ Port Harcourt ni ọjọ keji osu yii nínú ilé ìtura tí wọn dé si.

Baba Mohammed tí ó jẹ ọlọppaa to ti fẹ̀yìntì ni o ya oun lẹnu pé iru nkan bẹ́ẹ̀ le ṣẹlẹ si ọmọ oun nitori pe ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionShiite: Tinúbú, bá Buhari sọ̀rọ̀ kó tú ZakZaky sílẹ̀ kó tó pẹ́ jù

Nigba tí BBC kan si agbẹnusọ ajọ ọlọpaa ti Ipinlẹ Rivers, Omoni Nnamdi, o ni àwọn oluwadi tí ó wà labẹ ọga ọlọpaa patapata ni Abuja tí da awọn ọlọpaa meji naa nídè ni ọjọ Isẹgun.

O ni, "Wọn gbà wọn pada lai si ipalara kankan, ṣugbọn ìbọn ba ikan lara awọn ajinigbe naa, o si gb'ẹmi mi. Eyi tó ṣe pataki ju ni pe, awọn ọlọpaa meji naa ti pada si'le bayii."