6,409 olùwáṣẹ́ kọ̀wé fún iṣé ọlọ́pàá 200 ní ìpínlẹ̀ Niger

ọ̀ga ọlọ́ọ̀pá àgbà ní Nàìjírìà Ibrahim Idris Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ọlọ́pàá ní Nàìjírìà ní àyẹ̀wò tó ń lọ lọ́wọ́ ṣe pàtàkì láti rí i pé àwọn olùkọ̀wé fún'ṣẹ dá-ń-gájíá

Ẹgbẹrun mẹrin ninu nọmba yii ni wọn ti s'ayẹwo fun lọjọ Aje ati ọjọbọ to kọja

Awọn irinwo le ni ẹgbẹrun mẹfa o le mẹsan eeyan ni wọn kọwe fun iṣẹ ọlọpaa igba ni ipinlẹ Niger lapa aaringbungbun ariwa orilẹ-ede Naijiria.

Àwọn oṣiṣẹ to n ri seto igbaniṣiṣẹ tun ti se ayẹwo bakan naa fun ẹgbẹrun kan miran.

Igbakeji ọga ọlọpaa ni Naijiria lapa aaringbungbun ariwa, Alhaji Shuaibu Lawal Gambo, to ṣ'abẹwo si ipinlẹ Niger ni ọga ọlọọpa agba, Ibrahim Idris, ran awọn si ẹkun mẹfa orillẹ-ede Naijiria lati bojuto ayẹwo naa finnifinni ati lati wo ọna eto igbaniṣiṣẹ ṣiṣẹ ọlọpaa to n lọ lọwọ.

Ajọ to n ri si ọrọ ọlọpaa ni Naijiria, sọ pe ayẹwo to n lọ lọwọ ṣe pataki lati ri i pe awọn olukọwe fun'ṣẹ tó gbangba sùn lọ́yẹ́, yatọ si pe wọn pegede ninu ẹkọ ati ọpọlọ pipe fun iṣẹ ọlọpaa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: