Ọ̀yọ́: Àwọn ọ̀dọ́ da ìdìbò káńsù ru ní Ìbàdàn

Ìjà bé sílẹ̀ ní Olódó níbi ìdìbò káńsù
Àkọlé àwòrán Ìdìbò káńsù jákèjádè ìpínlẹ Ọyọ́

Ija ti bẹ silẹ ni agbegbe Olodo ni ilu Ibadan nibi ti ibo kansu ti n lọ lọwọ n'ipinlẹ Ọyọ.

Akọroyin wa ti o n tẹle bi nkan ṣe n lọ jábọ̀ pé, awọn ọdọ kan l'agbegbe naa sọ pe idibo ko ni waye ni ijọba ibilẹ Lagelu, afi bi wọn ba f'awọn lowo.

Ẹ̀wẹ̀, eto idibo naa ko di lilọ-bibọ ọkọ lọwọ.

Àkọlé àwòrán Eto idibo naa ko di lilọ-bibọ ọkọ lọwọ.

Akọroyin wa sọ di mimọ pe, ko si idiwọ fun àwọn ọ̀kọ̀ to ń kọja loju ọna marosẹ ní Ibadan bi ibo ti n lọ lọwọ.