Wọn ti bẹ̀rẹ̀ ìdìbò wọ́ọ̀dù kọọkan nipinlẹ Ọyọ

Àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìdìbò ń ṣiṣẹ́ bi
Àkọlé àwòrán Ìdí iṣẹ́ ẹni la ti ń mọni lọ́lẹ (OYSIEC)

Etò ìdìbò si ipò alága káńsù àti wọ́ọ̀dù ń lọ daadaa nipinlẹ Oyọ bayii nirọwọ-rọsẹ

Egbẹ òṣèlú PDP àti Accord kò kópa ninu rẹ̀.

Àkọlé àwòrán Ṣe àwọn Adelé kansu ti wọn tun ń dije ni yóò tún wọlé padà ni?

Opọlọpọ ninu àwọn oludije si ipò alága kansu ni wọn ti jẹ adelé tẹlẹ ni kansu wọn.

Àìkópa PDP àti Accord jẹ ki ọja APC maa ta daadaa ninu idibo yii nitori pe àwọn ololufe won kò wulẹ̀ jade wa dibo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé àwòrán Awọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ati Accord kò kópa nibẹ̀

Akọ̀ròyìn BBC Yorùba, Adedayọ Okedare, jábọ̀ pé àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú méjìlá ló ń kópa nínú ìdìbò nàá tó n wáyé ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, tó fi mọ́ àwọn ìjọba ìbílẹ̀ ẹlẹ́kùn kéèkè márùndínlógójì.

Ìdìbò náà yẹ kò wáyé ní ẹgbẹ̀rún máàrùn ún àti ọ̀tàlérúgba (5,260) wọ́ọ̀dù nipinlẹ Oyọ.